Aláboyún oṣù mẹ́jọ kú lẹ́yìn tí ejò bù ú jẹ nílé ìyàgbẹ́ ilé rẹ̀

Zainab Aliyu Balarabe padanu ẹmi rẹ lẹyin ti ejo bu u jẹ nile iyagbẹ to wa nile rẹ.

Oríṣun àwòrán, Usman Ahmad Nuraini

Àkọlé àwòrán, Zainab Aliyu Balarabe padanu ẹmi rẹ lẹyin ti ejo bu u jẹ nile iyagbẹ to wa nile rẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Arabinrin alaboyun kan, Zainab Aliyu Balarabe ti ku lẹyin ti ejo bu u jẹ nile iyagbẹ kan to wa nile rẹ nilu Kaduna.

Iṣẹlẹ naa lo waye lọjọ keji oṣu kini nile oloogbe to wa ni adugbo Kinkinau nipinlẹ Kaduna.

Oyun oṣu mẹjọ lo wa ninu obinrin naa.

Aburo ọkọ oloogbe to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Usman Ahmad Nuraini, sọ pe oloogbe Zainab lọ si ile iyagbẹ ni owurọ kutu ọjọbọ lati tura, lo ṣakiyesi pe nkankan ge e jẹ ni idi bo ṣe joko sori awo iyagbẹ.

Ṣugbọn ko kọbi ara si i, nitori pe ko mọ pe ejo ni. Lẹyin naa lo lọ ọ ṣaluwala, to si kirun.

Àkọlé fídíò, Snake Market: Àwọn òńtàjà ẹran ejò ní ẹran ejò dùn ju ẹran adìẹ lọ

Koda, o ti pada sori ibusun lati sun ko to o di pe oju ibẹ bẹrẹ si ni dun un gan, to si wú.

"Asiko yii lo to o mọ lọran, to si pe ọkọ rẹ, to si paṣẹ pe ki awakọ wọn o gbe e lọ sileewosan. Orogun rẹ sare gbe e lọ silewosan lasiko ti wọn n duro de awakọ, amọ o ni ẹpa ko boro."

"Wọn sare gbe e lọ sile iwosan, amọ gbogbo ileewosan ti wọn gbe e de lo sọ pe awọn ko ni aporo ejo lati lo fun un, nitori pe awọn eniyan kii ṣaba wa gba a.

Ati pe gbese lo maa n ja si fun awọn gẹgẹ bi ileewosan.

Ko to o di pe oloogbe ku, o sọ fun ọkọ rẹ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ pe oun ko gbọran mọ, bẹẹni oun ko riran mọ, eyi ti ko ribẹ ki ejo to o bu jẹ.

Ọgbẹni Usman sọ pe igbo wa ni agbegbe ti iṣẹlẹ yi ti waye, ti idile naa si ti gbe awọn igbesẹ kan, to fi mọ ni ilana abalaye lati dena ki ejo o maa ba wọ ile wọn.

Àkọlé fídíò, Ejo abami to n mu owo ni ajọ Jambu

Bakan naa ni wọn ko ri oyun oṣu mẹjọ to wa ninu rẹ doola.

Lẹyin ti wọn gbe oku obinrin naa pada sile ni wọn ranṣẹ pe awọn to n lo ilana ibilẹ lati mu ejo. Awọn wọnyii lo si ba wọn 'pe ejo naa jade' ninu awo iyagbẹ naa to wa.

Eyi ni fidio ti Ọgbẹni Usman ya lẹyin ti wọn gbe ejo naa jade kuro nile iyagbẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Obinrin naa fi ọmọ ọdun meji saye lọ.

Wọn ti sin obinrin naa ni ilana ẹsin Islam ni ana.