Ọmọ Ọgọta Ọdún kú sórí obínrin ní ilé ìtura ní Èkó

bẹẹdi

Oríṣun àwòrán, @Leohoppus

Àkọlé àwòrán, Orisírísí nkan lo maa n ṣẹlẹ lori ibusun ṣugbọn bii ti ere ifẹ di ero ọrun kọ ni kal;uku fẹ.

Obinrin kan ti ẹnikẹni ko i ti mọ orukọ rẹ lo ti fẹsẹ fẹ bayii nigba ti wọn ri oku okunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Raji.

Raji Adio ni kaadi idanimọ rẹ fihan pe ọmọ ọgọta ọdun nii ṣe.

Gẹgẹ bi ẹsun naa ti ri, Raji Adio, ti o jẹ ololufẹ ikọkọ arabinrin naa lo gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra nigba ti awọn mejeeji n sẹre ifẹ ni ile itura River Bank.

Ile Itura yii ni Ijọra Badia ni opopona Gasikiya, ni ilu Eko ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni nkan bi aago mẹjọ owurọ nibi ti Raji ti sanwo iyara kan fun igba diẹ.

Gẹgẹ bi ẹni ti o jẹ alakoso ile itura naa Williams Ekwzie, ti ṣalaye, o ni, lootọ ni awọn mejeeji sanwo lati wọ inu yara ti wọn si wọle.

O ni ko pẹ pupọ ni ikan lara awọn oṣiṣẹ wa ri wi pe obinrin naa sa sita lojiji lọna ti o mu ifunra dani.

Àkọlé fídíò, Oniru: Oba Oniru wàjà ní Eko tẹbí, tará ń ṣe ìdárò Alayeluwa

Alakoso ile itura naa fidiẹ mulẹ pe onibara ile itura yii ni Adio.

O ni nigba ti wọn gbiyanju lati sa tẹlẹ obinrin naa nitori ọna ifura to gba sa jade sita ni wọn rii pe ẹsẹ rẹ ya ti o si fẹsẹ fẹẹ.

bedi

Oríṣun àwòrán, @bedmate

Àkọlé àwòrán, Ko seni to n fẹ ku sile itura

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile itura naa John Chuks ni o tete pe akiyesi awọn eniyan si iṣẹlẹ naa ti obinrin naa si di awati.

Kete lẹyin eyi ni wọn gbe igbesẹ lati wa obinrin naa ri sugbọn pato ibi ti o gba kọja ni wọn ko mọ.

O tẹsiwaju pe, wọn ba oku ọkunrin naa ni ori ibusun ile itura naa ti ko si ẹni to mọ iru iku ti o pa lati ọwọ obinrin naa.

Ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹle ni wọn ti fi to Ọlọpa leti ti wọn si ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa ati lati wa obinrin naa ri.

Àkọlé fídíò, Brazil Yoruba: A n gbé àwọn ère Yorùbá káàkiri- Ọọni ti Ilé Ifẹ