Building Collpase: Ògiri kílààsì ìkẹ́kọ̀ọ́ wó pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méje ní Kenya

ile

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn obi ati alagbatọ ṣi n gbiyanju lati ṣawari awọn ọmọ wọn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn aláṣẹ ilé ìwé náà ní pé ogun akẹ́kọ̀ọ́ níkan ni àwọn ṣi ri yọ nínú ẹgbẹ̀rin akẹ́kọ̀ọ́.

Goerge Seda, ọga agab awọn ọlọpaa ẹkun yii lo fidiẹ mulẹ pe wọn ti ri oku akẹkọọ meje yọ ninu ile to dawo naa bayii.

Agbẹnusọ fun ijọba, Cyrus Oguna ni awọn akẹkọọ mẹtadinlọgọta ti wọn ti gbe lọ sile iwosan naa ti n gba itọju to yẹ.

Apejuwe bi iyara ikawe naa ṣe ri.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Egbẹ alagbelebu ni iṣe didoola ẹmi awọn eniyan yii ṣi n lọ lọwọ ni Nairobi.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ẹgbẹ alagbelebu pupa ni awọn ti si ibudo iforukọ silẹ lati pese iranwọ to yẹ fawọn obi ati alagbatọ ki wọn le maa fi wa awọn ọmọ naa.

Akoroyin BBC , Ferdinand Omondi to wa nibẹ ṣalaye pe nkan bii aago meje ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

O ni awọn olugbe agbegbe naa lo kọkọ dide iranlọwọ fawọn akẹkọọ naa ki ẹgbẹ alagbelebu pupa to ko awọn ti wọn ti ri yọ lọ sile iwosan Kenyatta National Hospital.

Iroyin ohun to ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin:

Awọn Ọlọpaa ilẹ Kenya ti idi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn ọmọ ile iwe Preciuos Tenant School ṣeṣe ti waọn meje si gbẹmi mi.

Oga Ọlọpa ilẹ naa, George Seda sọ wi pe Oku awọn ọmọ naa ni wọn ti ko lọ si ile iwosan.

ero

Oríṣun àwòrán, @Robertalai

Àkọlé àwòrán, Wọn ti n ri awọn kan fa ṣugbọn ẹru ṣi n ba obi ati alagbatọ

Iroyin wi pe ile iwe naa ni wọn fi patako ati orule lasan bo to o si dawo lulẹ ni kete ti awọn ọmọ naa bẹrẹ eto ikawe wọn lowurọ ọjọ Aje.

Alukoro fun Ijọba Orilẹ ede naa, Cyrus Oguna sọpe metadinlọgọta awọn ọmọ naa ni wón ti wa ni ile iwosan fun itọju.

Àkọlé fídíò, Yollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri

Ẹni ti o jẹ alakoso ile iwe naa, Moses Wainama Ndirangu sọ fun awọn Akọroyin pe o ti rẹ iganna naa ti o wa ni ẹba ṣalanga.

O ni Ẹgbẹrin ọmọ ni o wa ni ile iwe naa sugbon ti ko ju bii Ogun ti wọn ṣi ri lẹyin iṣẹlẹ naa.

Awọn ajọ alami pupa ti wa ni ki wọn pese aye silẹ ti awọn Obi ati Alagbatọ yoo fi mọ iye ọmọ ti o ku.

Awọn alaṣẹ ti fidiẹ mulẹ pe wọn ti ri oku akẹkọọ meje yọ ninu ile iwe naa.

Kilaasi ikawe kan lo wo lu awọn akẹkọọ ni Nairobi to jẹ olu ilu orilẹ-ede Kenya.

George Seda to jẹ adari awọn agbofinro ni ẹkun yii fidi ọrọ naa mulẹ pẹlu ibanujẹ.

John Karie to jẹ aṣoju ṣofin fun ẹkun yii ṣalaye pe laarọ oni ọjọ Aje ni ogiri kilaasi naa ya bo awọn akẹkọọ mọlẹ ni ile iwe Precious Talent School.

Wọn ni paanu ati pako ile iwe naa ti jẹ tẹlẹ ni eyi to si ya bo awọn akẹkọọ bi wọn ṣe wọle fun ikẹkọọ laarọ yii.

Moses Wainana Ndirangu to jẹ ọga agba ile iwe naa ṣalaye pe ṣalanga to wa lẹgbẹ iyara ikawe yii lo jẹ ki ogiri naa ma ni agbara mọ.

Moses ni ẹgbẹrin akẹkọọ ni wọn n wa sile iwe naa, ṣugbọn ogun pere ni awọn tii ri ṣajọ ti awọn si le sọ ni pato nipa wọn.

Wọn ti bẹrẹ si ni ka awọn ti ko wa sile iwe, ti wọn si n pe awọn obi ati alagbatọ lati mọ irin awọn akẹkọọ to ku.

Ndirangu ni o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn akẹkọọ pupọ ti sa lọ si agbegbe Dagoretti nibi to sunmọ ibi ti ile iwe naa wa.

Àkọlé fídíò, Yollywood:Ṣàgbẹ̀lójú yòyò ni ọ̀ps àwọn òṣèré- Ojopagogo