Osinbajo: Igbákejì ààrẹ Yemi Osinbajo ni ìwà àjẹbánu lẹ́nu iṣẹ́ ọba ló le jù nínú ìṣòro Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbakeji aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo ti ṣalaye pe yiyan awọn ọlọpọlọ pipe si ipo gbogbo lo tọna.
O ni ko yẹ ki a maa wo ti ẹya, ede tabi ohunkohun miran lo le mu ki orilẹ-ede Naijiria o ga de ibi ti o yẹ ko de.
Igbakeji aarẹ, Oṣinbajo woye ọrọ yii nibi idanilẹkọọ to gbe kalẹ fun ayẹyẹ ikẹkọgboye ẹlẹẹkẹjọ iru rẹ ti fasiti UNIOSUN nilu Oṣogbo.
O ni lilo ilana ọmọ onilu ati ọmọ onilẹ, (Quota system) fun yiyan awọn eeyan sipo iṣẹ ọba ati iṣejọba n ṣe ọpọ akoba fun idagbasoke Naijiria.
Ọjọgbọn Oṣinbajo sọrọ lori akori to pe ni 'Ọgọta ọdun Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede, Naijiria ṣi ni ilẹkun fun idagbasoke Afirika'.
O ni iṣoro to gogo ju ninu gbogbo idojukọ Naijiria lọwọ yii naa ni iwa jẹgujẹra ni ẹka iṣẹ ọba.
O ni iwa jẹgudujẹra naa gan an ti wa n dojukọ awọn to n gbogun tii bayii, bi o tilẹ jẹ wi pe o fi idi rẹ mulẹ pe iṣejọba aarẹ Buhari ko ni sun, bẹẹ ni ko ni wo lori ilakaka rẹ lati dẹkun iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria.
O ni ko si orilẹ-ede ti o le e de ibi giga lai jẹ pe o fi awọn to tọ si ipo to tọ dipo ọmọ wa ni ẹ jẹ ko ṣe.
Osinabjo ni o ṣeni laanu pe ọpọ awọn ọdọ lorilẹ-ede Naijiria ni ko mọ nipa asiko idẹra ti awọn aṣiwaju bii Awolọwọ, Nnamdi Azikiwe ati Ahmadu Bello gbe kalẹ fun orilẹ-ede Naijiria.
Ati pe ohun ti wọn ba ni akoko ipenija ati wahala to de ba orilẹ-ede yii ko kere rara.
Ninu iwoye rẹ, bi awọn ipenija wọnyii ṣe pọ si lo n ṣe afihan pe awọn akẹkọgboye tuntun lawọn ileewe giga gbọdọ ji giri.
Wọn gbọdọ ṣetan lati wa ojuutu si awọn iṣoro naa ki a lee kọ orukọ wọn sinu iwe iranti orilẹ-ede Naijiria.














