Abuja Bank Robbery: Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Ernest tí wọ́n ń wá.

Ernest Ewim

Oríṣun àwòrán, Guardian newspaper

Àkọlé àwòrán, Ọwọ́ ti tẹ ọ̀gbẹ́ni adigunjalẹ̀

Ọwọ sinku ọlọpaa ti tẹ arakunrin kan, Ernest, to jẹ igi lẹyin ọgba fawọn adigunjale to lọ ṣọṣẹ ni ile ifowopamọ kan laipẹ yi ni ilu Abuja, to jẹ olu ilu Naijiria.

Iroyin ni Ernest ọhun to n ṣiṣẹ ni ile igbafẹ ni o jẹ adari fun awọn adigunjalẹ mẹrin ti o lọ ṣọṣẹ ni First Bank to wa ni agbeegbe Mpape ni ilu Abuja.

Komisọnna Ọlọpaa ni ilu Abuja, Bala Ciroma lọ sọ bẹ fun awọn oniroyin pe ọwọ ti tẹ arakunrin naa.

Alukoro ọlọpaa nilu Abuja Manza Anjuguri fidi ọrọ yi mulẹ tio si ni awọn ṣi n fọrọ wa afunrasi naa lẹnu wo.

Ọkan lara awọn adigunjale

Oríṣun àwòrán, Buharist Reporter/Facebook

Kete ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ awọn adigunjale naa ni wọnti jẹwọ pe Ernest gaan ni firindiọkẹrẹ to ṣalude apade ati ja banki naa lole.

Ninu ọrọ tawọn iyoku rẹ sọ fọlọpaa wọ ni miliọnu meje naira ni awọn gbọkanle lati ji ko to di wi pe awọn ọlọpaa sigun bo ibẹ.

Larry Ehizo to jẹ osisẹ Banki naa wa lara awọn adigunjalẹ naa pẹlu arakunrin Timothy Joe, Princewill Obinna ati Elijah David to jẹ ọmọ ọdun jmọkandinlogun.