Nigeria Army: Bàbá Adamu tó jẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà tó dàgbà jùlọ jáláìsí

Army

Oríṣun àwòrán, @Nig Army

Àkọlé àwòrán, Bàbá Adamu tó jẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà tó dàgbà jùlọ jáláìsí

Lọdun 1918 ni wọn bi Adama Aduku labule Abejukolo-Ife ni ijọba ibilẹ Omaha ni ipinlẹ Kogi ni aarin gbungubn Naijiria.

Odun 1945 ni Aduku darapọ mọ iṣẹ ologun ni Naijiria to si ja ọpọlọpọ ogun ati ipese iṣẹ aabo gẹgẹ bii ọmọ ogun ilẹ Naijiria tootọ.

Lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2018 ni igbakeji aarẹ daa lọla.

Ojọgbọn Yemi Osinbajo ni o gbe ami ẹyẹ ti ileeṣẹ ologun Naijiria fi daa lọla fun un nibi ayẹyẹ Nigeria Army Day Celebration (NADCEL).

Ileeṣẹ ologun ati alaabo ilu lo kede iku akinkanju Aduku naa lori ayelujara lọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2020.

Lasiko ti Baba Aduku sọrọ lẹyin to gba ami ẹyẹ o kare ti ileeṣẹ ologun fun un lo sọ pe ara oun ṣi le daadaa koda lori ibusun paapaa ni eyi to pa ọpọ lérin in nigba naa.

aduku

Oríṣun àwòrán, @HQArmy

Àkọlé àwòrán, Bàbá Adamu tó jẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà tó dàgbà jùlọ jáláìsí

Aduku nigba aye rẹ sọ fawọn akọroyin pe oun ko deede darapọ mọ awọn ologun Naijiria.

O ni oun fẹ maa gbeja awọn eeyan ni nitori pe ọkunrin kan oloye kan ni abule ohun nigba naa.

O ṣalaye pe bi oun ṣe n bọ lati oko nirọlẹ ọjọ kan ni ọmọkunrin kan ti ko to mi ṣin aiya fun olori abule wa.

Aduku ni ọmọkunrin naa ni iwadii fihan pe ọmọ ogun ni ati pe Salikawa lorukọ rẹ.

Àkọlé fídíò, 2020: Ọdun 2020 yii ko nìí nira fún àwọn tó bá bẹ̀rù Olorun

O ni o na olori abule nitori pe ko baa gbe ẹru rẹ lọ sile to to maili mẹwaa sira wọn.

Àkọlé fídíò, 2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá

Eyi lo jẹ ki oun pinnu lati di ọmọ ogun nitori aṣaaju ijóba labule wọn ni ko si nkan ti ẹnikéni le ṣe fun sọja naa nitori pe aye ajẹrọrun ni awọn ọmọ ogun n jẹ nigba naa.

Àkọlé fídíò, 'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Baba Aduku ni koko to mu ohun foriti gbogbo ẹkọ ati ijiya lẹnu ikọṣẹ ṣọja ni ireti pe ti oun ba ṣetan, oun a gbẹsan ni abule.

Àkọlé fídíò, #Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria

O ni oun nii lọkan lati pada si abule ti ṣọja Salikawa n gbe nigba naa lati da seri aiya fun un nitori pe o yẹyẹ olori abule oun.

Àkọlé fídíò, Ọbẹ Ẹgusi sise ati jijẹ