Ẹni mẹ́ta wọ gbaga ọlọpàá nítori ajílẹ̀ tí wọ́n kó tà ní ọja Daleko ní Mushin

Oríṣun àwòrán, Punch
Ọlọpàá ìpínlẹ̀ Eko ti mú àwọn ọkùnrin mẹta kan Banjo Adeleke, James Dalex, àti Haladu Junaid ti wọ́n fẹ̀sun kan pé wọ́n ji ajílẹ̀ ọ̀ọ́dunrun àpò nígba ti wọ́n ja ilé ikẹru si ilé iṣẹ́ Iganmu Flour Mill.
Agbẹnuso ọlọpàá ìpínlẹ̀ Eko, Bala Elkana sọ èyí di mímọ nínú àtẹjáde kan to fọ́wọ́ si.
O ni pé ọga àgba patapata lori ètò ààbo ni ilé iṣẹ́ náà lo kan sí àwọn ọlọpàá pé àwọn ajílẹ̀ kan din ní ibi ti wọ́n ń ko ẹ̀ru si ti wọ́n si mú aṣọna tó wà lẹ́nu iṣẹ́ lọjọ ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ láti wa wi tẹnu rẹ̀.
Elkana ni nígbà ti ìwádìí bẹ̀rẹ̀ ni àwọn tọpasẹ àwọn ajílẹ̀ náà de ọja Dalekọ ni àgbègbè Mushin, eyi ti ko ṣẹyin awọn afurasi ibẹ.
Nibẹ ni wọn ti rii pe wọ́n ti tàá fún àwọn kan to wa láti ìpinlẹ̀ Kano ní ẹgbẹ̀run mẹ́rin Naira tí wọ́n si mú ènìyàn mẹ́ta to ní i ṣe pẹ̀lú rẹ̀ ati pe o lọwọ kan awọn oṣiṣẹ ibẹ ninu.
Bakan náà ni moto ti wọ́n fi ṣe àṣemaṣe naa ti wa ni àhámọ ọlọpàá, Elkana fi kun un pé àwọn yóò gbé àwọn ọdaran náà lọ si ilé ẹjọ laipẹ.
O sálàyé pé: Ní ọjọ kẹ́rinlelogun, oṣù kejila, ọdun 2019, ni déedé àago mẹrin àbọ̀ ní agọ ọlọpàá àgbègbè Bode Thomas gba ipe lati ọdọ oga agba to n ri si ààbò Iganmu Flour Mill pé wọ́n ja ilé ikẹ́ru si ilé iṣẹ́ náà ti wọ́n si jí ajilẹ̀ ọọdunrun apo lọ."
Kọmisọnna ọlọpàá ìpínlẹ̀ Eko, Hakeem Odunmosu ti dari ẹka to n ri si ìwádii (CIID) ti Yaba láti gba iṣẹ́ náà ki wọ́n si gbe wọ́n lọ ilé ẹjọ bi o ti yẹ.















