Awọn ọmọ Nàìjíríà bá aarẹ Buhari sọ̀rọ̀ lójú òpó BBC lórí ètò ààbò ìlú

Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, ètò ìlera ọ̀fẹ́, ọ̀pọ̀ ounjẹ, ìpèsè iṣẹ́, ìná ọba to duro déédé, àabò ẹmi àti dukia ní o jẹ́ orí nínú lẹ́ta ti àwọn ọmọ Naijira kọ sí àarẹ Muhammadu Buhari.
Wọn kọ lẹta yii ní ìdáhun si ibéèrè BBC Yoruba lójú òpó facebook rẹ̀ pé ti wọ́n ba ni ànfani lati kọ lẹ́ta si ààrẹ Buhari kíní wọ́n yoo kọ?
Nínú àwọn lẹ́tà ọ̀hun ní àwọn míràn tún ni kí ààrẹ kọju ija si iṣẹ òhun òṣì nítori pé iṣẹ́ àti òsì ló n bí ìwà ìbájẹ àti àjẹbanu to àwọn ọmọ Naijiria.
Bákan náà ni ọ̀rọ̀ ẹnu ibode Naijiria jẹ ẹlòmiran lógun bi wọ́n ṣe n bẹ ààrẹ kí o maa ṣi ẹnu ibode mọ rárá.
Wọn ni nítori pé ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria ló ti n gbin ìrẹsì lẹyin ti aarẹ Buhari ti ẹnu ibode pa.
Ilu gangan ni ọrọ naa, nitori bayiìí kọ lo ṣe koju si lọ́dọ́ Darfamola Adewale to ni bí ìrẹsi tiwantiwa ko ba di ẹgbẹ̀run mẹ́sàn an ki wọn kuku ṣi ẹnu bode pada

Oríṣun àwòrán, Tweet
Olori Yemisi nítirẹ̀ ní kò si ǹkan ti ọmọ Naijiria le kọ ti yòó ni ìtumọ si ààrẹ, O ni ọ̀rọ̀ ààrẹ dabi eleti kan to n ṣe òkú ìyá rẹ̀ ni, tí wọ́n ba n pee níbi ounjẹ yóò ma a lọ si ọ̀dọ̀ olorin.
Olubunmi Ajiboye ati Okanlawọn Olugbenga naa tun sọrọ pe:

Oríṣun àwòrán, Tweet
Awọn bii Ainu Lateef gbadura fun aarẹ Buhari ni nigba ti awọn bii Jacobson Adeniji, Toheeb Olawale, ati Oluseye Funmiso gba pe ko si ohun tuntun to le jade lọwọ Aarẹ Buhari.
Wọn ni alagidi ọkan kii gbọ ọrọ awọn eniyan ni loju ti wọn

Oríṣun àwòrán, Tweet
- Òṣèrébìnrin tí wọ́n bá fi ìbálòpọ̀ lọ̀ 'torí ìṣẹ́, kó bọ́ síta láti sọ̀rọ̀ - Kunle Afod
- Aisha Buhari, ohun mẹ́fà tò fi yàtọ̀ sí àwọn aya ààrẹ tó ti jẹ kọjá!
- Saraki àgbà ló kọ́ ilé yìí fáwa arúgbó kìí ṣe Bùkọ́lá- Arúgbó Ilọrin
- Bàbá akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ fi ṣ'oògùn owó ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo
Ẹ̀wẹ̀, awọn míran ni ó dàbi ẹni pe ọ̀rọ̀ ìjọba kò yé ààrẹ Buhari mọ.
Wọn ni o si ṣe pàtàkì ki wọ́n fi ipò ààrẹ silẹ láti lọ sinmi nilé, nígbà ti elo miran dáhun pe nnkan ti o ṣe pataki si òun ni pé, owó ti àarẹ fẹ́ ya, ó se pataki ki wọ́n ka àwọn ǹkan ti wọ́n fẹ́ fi owó náà ṣe ki wọ́n to yaa.

Loju Ogbeni Olatunbosun Abolarinwa ati Akinkunmi Akinpelu Kure Jnr ni ti wọn, iṣẹ aabo ilu, ọrọ pipalẹ awọn SARS mo ati pe ti arẹ ko baa rii ṣe mọ, o le pada sile.

















