WhatsApp: Àwọn fóònù wọ̀nyìí kò ni lè ṣe WhatsApp láti ọdún 2020

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tete maa yẹ foonu rẹ wo boo ṣe n ka iroyin yii boya ori yọ ọ.
Oju opo ikansiraẹni WhatsApp ko ni ṣiṣẹ mọ lori ọpọlọpọ ẹrọ alagbeka to ba ti dagba ju ọdun marun lọ.
Lati ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejilasun 2019, oju opo yii to gbajugbaja eyi tii ṣe ti Facebook ni eeyan biliọnu kan abọ n lo. Eyi si ni yoo kọkọ yọwọ atilẹyin wọn kuro lara awọn foonu ti oloyinbo n pe ni "Windows Phone" to n lo ilana iṣiṣẹ atijọ iyẹn operating system (OS).
Lara awọn foonu ti pipada lẹyin wọn eyi ti WhatsApp yoo ṣe yoo koba ni Nokia Lumia eyi to jẹ foonu to gbẹyin lati bẹrẹ si ni lo ilana iṣiṣẹ atijọ OS ti Microsoft Windows. Foonu bii Nokia Lumia 650 jade ni nkan bii dun mẹrin sẹyin ṣugbọn wọn ṣi n ta a lori igba titi di oni.
Ẹrọ alagbeka mii ti yoo tun ni imọlara ipada lẹyin ẹni yii latinu oṣu keji ọdun 2020 ni awọn iPhone to n lo ilana iṣiṣẹ iOS 8 ati awọn foonu Android to ni ẹda 2.3.7 tabi ko kere si i.
Lati ọjọ kinni oṣu keje, awọn eeyan to n lo Microsoft store ko ri WhatsApp gba lori ayelujara mọ. Eyi waye lẹyin ti WhatsApp fa awọn to n lo o leti lori foonu oni Windows pe wọn le dede ri awọn nkan amuy kọọkan ti ko ni ṣiṣẹ mọ.
Ileeṣẹ WhatsApp ni ati ṣe ipinu yii le gan ṣugbọn igbesẹ to tọ ti yoo jẹ kawọn eeyan le maa kan si ara wọn.
Eyi kii ṣe igba akọkọ ti ileeṣẹ WhatsApp yoo gbe iru igbesẹ yii.
Lọdun 2018, wọn yọwọ atilẹyin wọn lara ileeṣẹ foonu Blackberry atawọn foonu to n lo Windows ti atijọ.













