Coronavirus: Àlàyé rèé lórí ìdí tí wọn fi dá ìdánwò àbẹ́rẹ́ àjẹsára Oxford University dúró

Onimọ sayẹnsi ni inu ilé ìwádi Oxfordnínú osu keje ọdun yii

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àdánwò abẹ́rẹ́ àjẹsára Coronavirus ti AstraZeneca àti Fásitì Oxford ń ṣe lọ́wọ́, ni wọ́n ti dáwọ́ rẹ̀ dúró náà.

Ìdí ni pé ọ̀kan lára olùkópa nínú ètò ìdánwò náà ni UK ṣe ṣàìsàn, tí o jọ bi ẹni pé ó jẹyọ lati ara abẹ́rẹ́ ti wọ́n fún -un.

AstraZeneca ṣe àfíwé bí wọn 'se dá ìlò abẹ́rẹ́ náà dúró yìí gẹ́gẹ́ bi ǹkan tó tọ́ , tò sì máa ń wáye ni gbogbo ìgbà, pàápàá jùlọ tí àìsàn ti kò ṣee ṣe àpèjúwé rẹ̀ bá ṣelẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbogbo àbájáde abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ní àmójútó wà fún ní gbogbo àgbáyé.

AstraZeneca-Oxford ní abẹ́rẹ́ àjẹsára to dára jùlọ, nínú gbogbo àwọn n gbiyanju láti ṣe abẹ́rẹ́ àjẹ́sára jákèjádò àgbáyé.

Ibudo itọju alarun Coronavirus

Ipele àyẹ̀wò kẹta láti nnkan bi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn, ti kan ènìyàn tó lé ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n ènìyàn láti Amẹrika, UK, Brazil àti South Africa.

Ipele abẹ́rẹ́ àjẹsára kẹta yìí sába maa n kan àwọn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ènìyàn, ó sì le to ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ko tó pari.

Ìwé ìròyìn New York Times kede sita pé, àwọn tó fi ara wọ́n sílẹ̀ fún abẹ́ ìdánwo náà ni wọ́n ti ni àrùn transverse myelitis.

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Èyí ni ààrùn tó maa n dàmú ọ̀pá ẹ̀yin, ó sì tún le yí sí ààrun míràn tó lágbára.

Ẹ̀wẹ́, wọ́n kò ti mọ nǹkan to n fa àisàn náà, àwọn olùwádìí aladani naa ti lọ wá ẹ̀dà ọ̀rọ̀ tó ba jẹ́ pé ó jọ mọ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára ọ̀hun

Bákan ní ààrẹ ilẹ̀ Amerika Donald Trump ti ni, òun fẹ́ kí àbẹ́rẹ́ àjẹsára náà de sí ilẹ̀ Amẹrika kò tó dí ọjọ́ kẹta osù kọkanlá ọdún 2020.

Eyi sí ti kó ìpayà bá ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹrika pé, ọ̀rọ̀ òṣèlú fẹ́ bórí ilera àwọn ènìyàn, pàápàá jùlọ lórí ọ̀rọ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára náà.

Àkọlé fídíò, Coronavirus vaccine: How close are you to getting one?

Ní ojọ́ Iṣẹgun, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́sàn tó n ṣeto àbẹ́rẹ̀ àjẹsára náà ń fi ọkàn ara ìlú balẹ̀ pé, ìlànà iṣẹ̀ ìṣègùn àti sáyẹnsì kò ni mẹ́hẹ, bí àwọn ṣe ń wá abẹ́rẹ́ ajẹsára fún Covid-19.