Alaafin: Ọmọ ọdún 17 ní Ayaba Abibat Adeyemi nígbà tó fẹ́ ọkọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ọba alade nilẹ Yoruba jẹ ẹni ọwọ ati ẹni apọnle, ti awọn araalu si maa n bu ọla to pọ fun wọn.
Lara awọn ohun tawọn ọba yii si maa n fi se ọla ni nini olori tabi ayaba puọ lọọdẹ wọn.
Bẹẹ si ni ọmọ sori ni aafin Ọyọ, nibi ti Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta ti ni ayaba to pọ lọọdẹ.
- N kò mọ bí wọ́n ṣe n bá obìnrin sọ̀rọ̀ ìfẹ́ - Aláàfin
- Kí ló mú Olorì Badrat Ajoke kúrò ní ààfin Oyo lọ́jọ́ Iléyá?
- Wo ọ̀nà tí àwọn ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’ gbà dé ààfin Ọyọ
- Èyí ni àwọn arẹwà ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’, àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- Kí ló wà ní ìdí igbá tí àwọn olorì Aláàfin máa ń tí lóde Ọ̀yọ̀
- Wo àwọn olorì àgbà mẹ́rin tí Aláàfin ń wárí fún
Amọ ko si bi awọn ayaba naa ti pọ to ti ayaba akọkọ ko ni da yatọ, idi si niyi to fi se pataki lati mọ nipa aya akọkọ ti ọba Adeyemi gbe sile.
Ta ni aya akọkọ fun ọba Adeyemi:
Abibat Nihinlola Oladele ni orukọ abisọ olori agba laafin Ọyọ lọwọlọwọ bayii, ọjọ kẹtalelogun osu Kejila ọdun 1938 si lo dele aye.
Ọmọ bibi agboole Lagunna ladugbo Agunpopo nilu Ọyọ ni Olori Abibat, kii si se ajeji rara si AafinỌyọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Nigba to fẹ Lamidi Olayiwola Adeyemi lo di Abibat Nihinlola Adeyemi.
Iya Adodo ni ọpọ eeyan n pe, gẹgẹ bo se wọpọ lati maa da awọn olori agba pe laafin, eyi to da lori ojuse wọn.
Olori agba naa, to ti le ni ẹni ọgọrin ọdun kii se iyawo mọ fun ọba alade naa, a si lee pe ni iya rẹ nitori aajo ati itọju to ti n se fun lati ọpọ ọdun wa.
Bẹẹ si ni Iya Adodo ni ọpọ ojuse to n se ninu aafin, eyi ti asa Yoruba gbe le lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Ọpọ eeyan si lo ri olori agba bii ẹni to ko ni mọra, iya rere ati onifarada ẹda, ti kii kanra mawọn ọdọ ati olori kekere.
Bawo ni Lamidi Adeyemi ati Abibat se pade?
Gẹgẹ bi a se gbọ, eeyan nii mu ni mọ eeyan lọrọ ọba Adeyemi ati aya rẹ akọkọ nitori lati ipasẹ aburo rẹ obinrin ni wọn ti pade.
Ile ẹkọ girama kannaa ni Abibat ati aburo Lamidi naa n lọ, ọdun 1956 si ni wọn jọ pade.
Olori Abibat ko si ju ọmọ ọdun mẹtadinlogun lọ nigba ti wọn mọ ara wọn, ti wọn si se igbeyawo lasiko ti obinrin naa wa nile ẹkọ girama.
Ni asiko yii, ọba Adeyemi ko tii gori itẹ awọn baba nla rẹ, ti ko si ti ye rara pe ori ade ni oun bi o tilẹ jẹ pe ọmọ Alaafin ana ni.

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn mejeeji ko lee sọ ibi ti ori n ba ẹsẹ wọn re, sugbọn pẹlu ifẹ nla to wa laarin wọn, wọn gba pe ọla yoo dara.
Ọjọ ori ọba Adeyemi ati olori akọkọ rẹ sunmọ ara wọn pupọ, osu lasan si ni wọn gba lọwọ ara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olòrì Alaafin Adeyemi àtàwọn tó bá fẹ́ fẹ́ wọn
- "Kòríkòsùn lèmi àti Alaafin ṣùgbọ́n kété táwọn kan kẹ́ẹ́fín pé èmi láàyò ni gbogbo nǹkan dojúrú." Badirat Ajoke, olorì tẹ́lẹ̀ kẹ́dùn Alaafin
- Njẹ́ o mọ̀ pé láàrín ìṣẹ́jú méjì, ọmọdé kan ń kú nítorí àìsàn ibà??
- Àjọ NDLEA nawọ́ gán ọkùnrin tó lọ́wọ́ nípa ẹ̀sùn N3bn egbògi Tramadol tí Abba Kyari ń kojú
Osu Kẹwa ọdun 2020 ni Alaafin Adeyemi yoo pe ẹni ọdun mejilelọgọrin, nigba ti Ayaba Abibat yoo pe ẹni ọdun mejilelọgọrin losu Kejila ọdun.
Olori Abibat tẹle ọkọ rẹ silu Eko nibi to ti n sisẹ bii osisẹ nileesẹ adojutofo kan.

Oríṣun àwòrán, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta
Nibẹ si ni Olori agba yii ti kọ isẹ aransọ taa mọ si Telọ, ilu Eko yii si ni wọn bi ọmọ mẹta si.
Lẹyin ti ọba Adeyemi gori itẹ awọn baba rẹ ni wọn tun bi obinrin meji si, ti apapọ ọmọ ti wọn bi jẹ marun, obinrin mẹta ati ọkunrin meji.
Iya Adodo lo bi ọmọbinrin ati ọmọkunrin akọkọ fun Ọba Adeyemi, eyi ta lee pe ni Bẹẹrẹ ati Arẹmọ laafin Ọyọ.
Gbogbo awọn ọmọ to wa laarin Olori Abibat ni wọn n se daadaa, ti wọn si ti laami laaka ninu isẹ ti wọn yan laayo.
Afihan pe Olori Abibat Nihinlola Adeyemi koni mọra lo farahan pẹlu bo se se koriya fun ọkọ rẹ lati ni ayaba pupọ, ti ko si si ija laarin wọn.
A wa gbadura pe Ọlọrun yoo tubọ lọra ẹmi Alaafin ati Olori rẹ agba, ki wọn le lo ara wọn gbo si.
- Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tí kìí ṣe ọmọ káàárọ̀ oòjíire
- Ǹjẹ́ o mọ àwọn òṣèré bí Oyin Adejọbi, Funmi Martins àtàwọn míì tó ti dágbére fáyé?
- Ìtàn ìgbé ayé Isola Ogunsola 'I-sho Pepper', ògbóǹtagí òṣèré tíátà tó s'eré Yorùbá yíká Nàìjíríà
- Kí ló wà ní ìdí igbá tí àwọn olorì Aláàfin máa ń tí lóde Ọ̀yọ̀
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá













