Alaafin of Oyo: Badirat Ajoke, olorì Alaafin tẹ́lẹ̀ ní òun lààyò Alaafin kó tó wàjà, ṣùgbọ́n àwọn kan ló da árín wọn rúní kété tí wọ́n ni kete ti wọn kẹẹfin ẹni ti ẹ yan laayo

Badirat Ajoke, olori alaafin tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, queenola

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Kii ṣe iroyin mọ pe Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ti ju awa silẹ o si ti darapọ mọ awọn alalẹ.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀

Bẹẹni oniruuru ọrọ ikẹdun lo si ti jade lati ẹnu ẹbi, ara, ọrẹ atawọn mọlẹbi rẹ gbogbo titi kan awọn mutumuwa nilẹ Yoruba ati lokeere.

Pataki lara awọn olori to ti wọ iyẹwu ti iku Baba yeye ni Badirat Adeyẹmi jẹ bi o tilẹ jẹ wi pe nigba to di saa kan, ina ko wọ laarin oun ati ọba naa mọ wọn si pinya.

Ninu atẹjade kan to wa fi si oju opo Instagram rẹ lati daro Alaafin Adeyẹmi.

Olori Badirat Adeyẹmi ni oun mọ pe ninu gbogbo orekelẹwa Baba, oun ni aayo rẹ.

Ati pe ni kete ti awọn olori yoku atawọn eeyan kan laafin Ọyọ kẹẹfin pe oun gan ni Ọba Adeyẹmi Kẹta fẹran ju ni wọn gbogun dide eleyii to fa edeaiyede laarin oun ati Ọbalaye naa.

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

O ni gẹgẹbi o ṣe jẹ pe ọmọ ọdun mọkandinlogun ni oun jẹ nigba ti Kabiyesi Alaafin gbe oun niyawo, okun ifẹ to wa laarin awọn mejeeji dabi ti awọn ibeji to lẹpọ lati ọrun waye ni.

"Bi mo ba n sọ fun awọn eeyan irufẹ okun ifẹ to wa laarin wa bii ti ibeji to lẹpọ latinu iya wọn...pẹkipẹki la sun mọra bi ọrẹ ṣugbọn ni kete ti wọn kẹẹfin ẹni ti ẹ yan laayo ni gbogbo nnkan dojuru."

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

O ni Alaafin jẹ Baba, olukọ, awokọṣe ati ọkọ ti ẹnikẹni ko lee dabii rẹ fun oun ati pe oun ko tii mọ ọna lati gba sọ fun awọn ọmọ awọn nitori pe awọn naa `ti n ni imọ pupọ nipa iru eeyan pataki ti baba wọn jẹ.

Aworan atẹjade ti Olori Badirat Ajọkẹ kọ nipa Alaafin Adeyẹmi loju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, Queenola/ instragram

Ta ni Olori Badirat Adeyẹmi?

Ọkan lara awọn orekelẹwa ẹlẹ Alaafin ti ilu Ọyọ ti opo rẹ yẹ lopin ọsẹ ni Olori Badirat jẹ ki o to ko kuro laafin Ọyọ lọdun 2020.

Oniruuru awuyewuye lo waye nigba naa lori igbeyawo oun ati Alaafin nigba naa.

Olori Badirat Ajoke funra rẹ lo sọ ọ sita nigba naa pe oun ti kuro ni aafin Ọba Lamidi Adeyemi III.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

O yan ọrọ naa lasiko to n fi atẹjisẹ dahun oriṣiri'si ibeere ti awọn ololufẹ rẹ n bi i lori ayelujara ibaraẹnidọrẹ Instagram rẹ ni.

Igba akọkọ si niyii ti Badirat sọ ọrọ ni taara pe oun ti kuro ni aafin ilu Ọyọ. O ma n fi owe sọrọ ni lati igba ti iroyin naa ti jade ni bi oṣu diẹ sẹyin si asiko naa.

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé

Nigba ti ẹnikan beere lọwọ rẹ pe ṣe nitori awuyewuye pe oun ati Wasiu Ayinde n fẹ ara wọn, lo ṣe kuro ni aafin, Badirat sọ pe oun ti kuro ni aafin ṣaaju iroyin naa.

Oṣu diẹ sigba to ko kuro laafin nigba naa ni iroyin sọ pe olori Badirat Ajọkẹ, ati gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde K1 n fẹ ara wọn.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Kí ni Ìjálá láàrin àwọn ewì alohùn àti bí wọ́n ṣe ń sun-ún?

Nigba ti wọn tun bi i pe ẹkọ wo lo mu kuro ni aafin nigba naa, o ṣalaye pe ẹkọ ti oun kọ kuro ni aafin ni pe "ma ṣe finu tan ẹnikẹni. Awọn ọmọ rẹ ni ọrẹ rẹ timọ-timọ".