Abba Kyari: NDLEA sọ pé nígbà tí ọkùnrin yìí ń lọ láti Abuja sí Eko

Afam Mallinson Ukatu àti Abba Kyari

Àjọ tó ń gbótunti lílo egbògi olóro ní Nàìjíríà, (NDLEA) ní àwọn ti nawọ́ gan ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Afam Mallinson Ukatu.

Ukkatu ni wọ́n fẹ̀sùn kàn wí pé ó lọ́wọ́ nínú egbògi Tramadol èyí tí ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, Abba Kyari lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

Agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní àwọn nawọ́ gán Ukatu ní pápákọ̀ ọkọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Eko nígbà tó fẹ́ wọ ọkọ̀ lọ sí ìlú Abuja lọ́jọ́ kẹtàlá, oṣù kẹrin, ọdún 2022

Babafemi ní ìwádìí fi hàn wí pé Ukatu tó jẹ́ alága ilé iṣẹ́ Mallinson máa ń kó onírúurú ẹ̀ya oògùn olóró Tramadol Hydrochloride èyí tí mílígírààmù rẹ̀ tó ọgọ́fà, igba, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó ṣàlàyé wí pé Ukatu ń lo ilé iṣẹ́ ìpògùn tó ti ń ṣe parasitamọ́ọ̀ àti ilé iṣẹ́ ike láti máa fi kó àwọn oògùn olóró wọ Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Ẹ̀sùn kíni wọ́n fi kan Ukatu?

Ó fi kun wí pé láti ọdún tó kọjá ni àjọ NDLEA ti ń fojú fínlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Ukatu lẹ́yìn tí wọ́n gba páálí Tramadol márùn-ún lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ rẹ̀ kan lọ́jọ́ kẹrin oṣù karùn-ún, ọdún 2021 nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ tà á fún àwọn òṣìṣẹ́ ọlọ́pàá kan.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé wí pé mílíọ̀nù mẹ́tàdínlógún ni wọ́n dúnàádúrà sí láti páálí kọ̀ọ̀kan.

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

Ó tẹ̀sìwàjù pé lẹ́yìn tí àwọn fi póró òfin gbé Pius Enidom àti Sunday Ibekwete tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ Ukatu ni wọ́n mú àwọn lọ sí ilé ìkọ́jàpamọ́ sí Mallinson níbi tí àwọn àwọn ti rí páálí Tramadol mẹ́tàdínnígba òmíràn gbà.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀

Babafemi ní gbogbo iye páálí àwọn Tramadol tí wọ́n gbà lọ́wọ́ Ukatu lọ́jọ́ kan jẹ́ bílíọ̀nù mẹ́ta náírà.

Bákan náà ló fi kun wí pé akoto owó mẹ́tàlélọ́gọ́run ni Utaku ń lo láti fi wọ owó ní akoto owó olówó.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì, ọdún 2022 ni àjọ NDLEA ti nawọ́ gán Abba Kyari lẹ́yì tí wọ́n kéde rẹ̀ bí ẹni tí wọ́n ń wá fẹ́sùn wí pé ó lọ́wọ́ nínú gbígbé egbògi olóró wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti orílẹ̀ èdè Brazil àti Singapore.

Láti ìgbà náà ni Kyari ti ń kojú ẹ̀sùn lílọ́wọ́ nínú gbígbé egbògi olóró wọ orílẹ̀ èdè yìí tó sì ti ń jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abba Kyari ní òun kò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun, ilé ẹjọ́ kọ̀ láti fún-un ní ìdáǹdè.

Ilé ẹjọ́ ní kó máa wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje títí ìgbà mìíràn tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ yóò máa wáyé.