NDLEA VS ABBA KYARI : Iléẹjọ́ gigá sún ìgbẹ́jọ́ béèlì Abba Kyari di ọjọ́ Kẹ́rìnlá oṣú kẹ́ẹ́ta

Abba Kyari

Olúwa mi, mi ò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn mí - Abba Kyari

Ni bayii ti igbejo si lọwọ lori esun ti ajo to n gbogun ti oogun oloro lorile ede Naijiria (NDLEA) Fi kan Abba Kyari.

Lasiko ti igbejo naa n lọ lọwọ, lara awon eniyan mefa ti ajo NDLEA gbe wa sile ejo ti gba pe awon jebi esun ti won fi kan wọ́n ṣubon Abba Kyari ni oun ko jebi esun ti won fi kan an.

Ile ẹjọ giga nilu Abuja ti gbẹjọ ẹsun onigun mẹjọ ti wọn fi kan ọga ọlọpaa Abba Kyari.

Ninu igbẹjọ to waye ọhun, adajọ gbọ bi Kyari ṣe sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an lori gbigbe oogun oloro.

Igba akọkọ ree ti awọn mọlẹbi rẹ yoo fojukan lati igba to ti wa ni ahamọ.

Bo tilẹ jẹ pe awon agbejoro ijoba fẹ ki wọ́n gbe Abba Kyari lọ si ọgba ẹwọn ṣugbọn agbẹjọro rẹ bẹ ile ẹjọ lati jẹ ki Abbba Kyari wa ni odo ajọ NDLEA niluu Abuja.

Adajọ gba pe ki wọn gbe pada si ahamọ lọdọ ajọ NDLEA dipo ọgba ẹwọn ti wọn fi si.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Agbẹjọro Kyari Kanu Agabi, SAN, sọ pe ki adajọ faaye gba gbigba oniduro Kyari.

Lẹyin atotonu to pọ, adajọ gba lati gbọ ẹjọ gbigba beeli rẹ lọjọ kẹrinla oṣu yii.

Ẹwẹ, ni ti awọn meji mii ti wọn ko wa sile ẹjọ lori ẹsun kiko oogun oloro wa si Naijiria, wọn ti gba pe awọn jẹbi tori naa ni wọn yoo fi gbọ ẹjọ naa lọtọ si ti Kyari.

Abba Kyari

Kí ló ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀?

Oni ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2022 ni ajọ NDLEA yoo gbe ọga ọlọpaa, Abba Kyari lọ sile ẹjọ giga kan niluu Abuja lori ẹsun pe o lọwọ ninu gbigbe oogun oloro.

Kyari yoo kawọ pọn rojọ niwaju adajọ Emeka Nwite pẹlu awọn mẹfa mii nibi ti gbogbo wọn yoo ti sọ tẹnu wọn lori ẹsun mẹjọ ọtọtọ ti NDLEA fi kan wọn.

NDLEA ni Kyari atawọn oṣiṣẹ rẹ kan fi ọwọ kan oogun oloro cocaine ti iwọn rẹ to 21.25kg ti wọn gba lọwọ awọn to gbe oogun naa, iyẹn Chibunna Patrick Umeibe ati Emeka Alphonsus Ezenwanne.

Wọn ni awọn afurasi naa ṣe si ẹsun naa ni ọọfisi ọga agba ọlọpaa, IGP niluu Abuja, eyii to lodi si ofin ajọ NDLEA, abala '14(b) CAP 30' ti wọn gbe kalẹ lọdun 2004.

Abba Kyari in court

Wọn ni Kyari gbiyanju lati fun ọga NDLEA kan ni riba ti iye rẹ to $61,400 owo ilẹ okeere nile ounjẹ kan niluu Abuja, ki ọga NDLEA naa ma baa ṣe ayẹwo oogun oloro ti wọn gbẹsẹle.

NDELA tun sọ fun ile ẹjọ pe Umeibe ati Ezenwanne gbimọpọ pẹlu ọgbẹni kan, IK to tin a papa bora bayii, lati gbe egboogi cocaine ti iwọn rẹ to 21.35kg wọ Naijiria eyii to lodi si ofin NDLEA abala '11(d) CAP N30' ti ijọba apapọ gbe kalẹ lọdun 2004.

Lara awọn iwe ẹsun naa ke pe "Iwọ Abba Kyari atawọn mii lọwọ ninu gbigbe egbogi cocaine ti iwọn rẹ to 17.55kg lai gba aṣẹ lọwọ ijọba, eyii to lodi si ofin."

Wọn ṣi n wa Kyari l'Amẹrika

Ẹwẹ, adajọ agba Naijiria, Abubakar Malami ti buwọlu aṣẹ kan pe ki wọn fa Kyari le ijọba ilẹ Amẹrika lọwọ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu afurasi onijibiti ori ayelujara, Ramon Abbass Hushuppi.

Ijọba Amẹrika n reti ki Kyari wa jẹjọ lori ẹsun iditẹ lati lu jibiti ori ayelujara ati wiwọ ike.

Abba Kyari

Ninu oṣu Kẹrin ọdun 2021 ni adajọ ile ẹjọ kan ni California paṣẹ ki wọn lọ gbe Kyari wa lati wa sọ tẹnu rẹ.

Abba Kyari

Malami ni lẹyin aṣẹ yii ni ọọfisi ijọba Amẹrika to wa ni Naijiria bere pe ki ijọba Naijiria fa Kyari le awọn lọwọ lati lọ jẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni idi ti oun ṣe ni ki wọn gbe Kyari lọ ilẹ Amẹrika ni pe ko si ẹjọ kankan to n jẹ ni Naijiria lọwọ bayii, nitori naa akoko ti to fun lati lọ koju ẹsun ti wọn fi kan nilẹ ọhun.Abba Kyari yóò fojú balé ẹjọ́ lónìí, ohun tí yóò wáyé níbè rèé