Abba Kyari: Ohun méjé tí o kò mọ̀ nípa Kyari rèé

Abba Kyari jẹ ọkan gboogi lara awọn ọlọpaa ti okiki rẹ kan kaakiri Naijria, amọ nnkan ko ṣenu ire fun lati igba ti orukọ rẹ ti jẹyọ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu afurasi onijibiti ori ayelujara, Hushpuppy.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ ni ko lọ rọọkun nile lẹyin ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI, ni ko wa sọ tẹnu rẹ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu Hushpuppy.
Wayi o, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti fa Kyari le ajọ NDLEA lọwọ lẹyin ti NDLEA sọ pe o n ba awọn to n gbe oogun oloro dowopọ.
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- A ṣì lè yanjú ọ̀rọ̀ Ukraine ní ìtùbí-ìnùbí - Russia
- Ki lo ṣokunfa ikọlu to n waye si ẹni to ba wọ aṣọ Sunday Igboho tabi Yoruba Nation n'Ibadan?
- Oríṣìíríṣìí aṣọ aláràǹbarà láwọn òṣèré tíátà fi ṣe àyájọ́ ọjọ́ olólùfẹ́
- Makinde buwọ́lu Sẹ́nẹ́tọ̀ Lekan Balogun gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun
Awọn ohun meje to yẹ ki o mọ nipa Abba Kyari ree
- Wọn bi Abba Kyari lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 1975, niluu Maiduguri, ni ipinlẹ Bornu
- O kẹkọọ gboye ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Maiduguri ati ile ẹkọ awọn ọlọpaa to wa ni Wudil, Kano lọdun 2000.
- Okiki rẹ bẹrẹ si n kan lẹyin ti ọwọ rẹ tẹ awọn gbajumọ ajinigbe kan bi Evans, Wadume, ati bẹẹ beẹ lọ.
- Kyari kawe gboye ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Miduguri
- O jẹ igbakeji kọmiṣọnna ọlọpaa ati ọkan lara awọn ikọ akọṣẹmọṣẹ afimufinlẹ ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ko sọdi, IRT, ni olu ileeṣẹ naa to wa niluu Abuja
- Kyari ti fi akoko igba kan ṣiṣẹ gẹgẹ bii alakoso ẹka to n gbogun ti idigunjale, SARS, ni ipinlẹ Eko
- Lara awọn aṣeyọri Kyari ni bi ikọ rẹ ṣe fi ṣikun ofin mu awọn adigunjalẹ to kọlu ile ifowopamọ kan niluu Offa, ni ipinlẹ Kwara, nibi ti ẹmi eeyan mọkanlelọgbọn ti sọnu
Bawo ni ọ̀rọ̀ Abba Kyari ati Hushpuppi Ramoni Igbalode ṣe jẹ́?
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu ọdun 2020 ni FBI fi ṣikun ofin mu Hushpuppy niluu Dubai ti wọn si gbe lọ silẹ Amẹrika lati lọ jẹjọ lori ẹsun jibiti ori ayelujara.
Lasiko ti FBI n ṣe iwadii naa ni ọrọ kan Abba Kyari, eyii to mu ki adajọ Otis Wright ni ko wa sọ tẹnu rẹ.
Iṣẹlẹ naa lo mu ki ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni ko lọ rọọkun nile, ko si fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bii adari ajọ ITR.

















