Sunday Igboho supporters: Ki lo ṣokunfa ikọlu to n waye si ẹni to ba wọ aṣọ Sunday Igboho tabi Yoruba Nation n'Ibadan?

Oloye Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Ọkan lara awọn ọmọlẹyin Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si "Sunday Igboho", Ọmọọba Omiyale Ademọla ti ke gbajare sita.

O ni pe awọn eeyan kan ti fọn si igboro ilu Ibadan ti wọn si deede n ṣe ikọlu si ẹnikẹni ti wọn ba ri to wọn aṣọ ti o ba ni akọle 'Sunday Igboho' tabi ipe fun idasilẹ orilẹede Oodua, 'Yoruba Nation' lara.

Ninu ọrọ ti o ba BBC Yoruba sọrọ l'ọjọ Aje nile Sunday Igboho to n bẹ ni agbegbe Soka nilu Ibadan, Ademọla ni iṣẹlẹ naa ti n waye fun igba diẹ bayii.

Ni eyi to jẹ wi pe ẹnikẹni ti o ba ti wọ aṣọ Oloye Sunday Igboho tabi to de fila Yoruba Nation, to ba jẹ pe ori okada ni wọn a jaa bọlẹ, wọn a ṣee leṣe, wọn a gun un yanayana.

Awọn ẹri wa nibi, to jẹ ẹri maa jẹ mi niṣo".

Ademola ni pe: "Nigba ti awọn ọrọ yii bẹrẹ, Mọlete lo ti kọkọ bẹrẹ. Eeyan wa n jade lọ ibi iṣẹ rẹ, kodaa ọkada rẹ ṣi wa pẹlu wọn ti wọn ko ti i gbee silẹ titi di oni. Ki i ṣe ọlọkada, o n lọ ibi iṣẹ ẹni.

Wọn dẹ daa duro, wọn dẹ ṣaa yanayana".

Àkọlé fídíò, Kong Thong: Àwọn òbí máa ń súfèé kọrin tàbí hu láti pe ọmọ tó bá dàgbà

Ademọla tẹsiwaju pe ikọlu to waye gbẹyin ni nnkan bi i aago mẹsan aabọ owurọ ọjọ Abamẹta ṣẹlẹ si arakunrin kan ti o maa n se asun fun awọn eeyan ninu ile Oloye Sunday Igboho, ti o si tun un ṣe iṣẹ afẹfẹ gaasi ẹro to n mu ile ati ọkọ tutu.

Arakunrin naa n lọ si ẹnu iṣẹ l'owurọ ọjọ Abamẹta. Nigba to de ibudoko to n bẹ ni agbegbe Soka ni awọn eeyan kan wọọ bọlẹ lori ọkada pe ọmọ Igboho ni.

Arakunrin naa beere ẹṣẹ ti oun ṣẹ, wọn ni, "Ẹyin lẹ ni ko ni si eto idibo lọdun 2023, ẹyin lẹ ni Yoruba kan ni. Ẹ pe ọga yin nisin, ṣebi o n bẹ ninu ẹwọn".

Ọkunrin to farapa nile Sunday Igboho

Lẹyin eyii ni wọn bẹrẹ sini na arakunrin naa titi ti wọn fi gun un ni nnkan ni agbọn, ti ẹjẹ si boo.

Ademọla fi kun ọrọ rẹ pe wọn gbe arakunrin naa lọ si agbegbe New Garrage lẹyin ti wọn luu tan.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

O ni lẹyin eyii ni awọn dede n gburo awọn ọkọ kan ti o to tẹle ara wọn ti wọn si sare kọja niwaju ile Sunday Igboho.

Eruku awọn ọkọ naa ti wọn ri lo mu ki ọkan ninu awọn to n gbe ile Sunday Igboho ti wọn pe orukọ rẹ ni "Kokoro" pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn gbe ara wọn si ori okada ni meji meji, lẹpa awọn ọkọ naa lọ.

Ọkunrin to farapa nile Sunday Igboho

Ademọla ni bi awọn ọkọ naa ṣe jade si agbegbe Soka ni wọn mu ori le ọna Iwo Road ti wọn di doju ibọn kọ awọn to n lepa wọn lati ile Sunday Igboho.

Ninu iṣẹlẹ yii ni arakunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni "kokoro" ti padanu ẹmi rẹ, ti awọn to ku si fi ara pa. Titi di asiko yii sini wọn n wa ibi ti oku arakunrin naa wa.

Àkọlé fídíò, 'Ìyá Tíṣà lòdì sí kí n mutí, fagbó tàbí sìgá'

Bo tilẹ jẹ wi pe Ademọla ko da oruko ẹni kan ni pato, o ni oun mọ awọn to yin ibọn naa.

O kesi Gomina Ṣeyi Makinde lati gbe igbesẹ ti to tọ lori eto aabo n'ipinlẹ Ọyọ, nitori ipenija eto aabo ti dawọ duro n'ipinlẹ naa ki ijọba tuntun to gun ori aleefa.

Àkọlé fídíò, Ìdíje ata tútù: Jẹ ata 50, ko gba góólù gírámù mẹ́ta