Building collapse Yaba Lagos: Wọ́n ti rí òkú eèyàn mẹ́ta yọ kúrò lábẹ́ ilé tó dàwó ní Yaba

Ile to dawo ni Yaba
Àkọlé àwòrán, Ile to dawo ni Yaba

Ajọ Lagos State Emergency Management Agency (LASEMA) tó n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko ti sọrọ lori ibi ti ọrọ de duro nipa ile to dawo ni agbegbe Yaba ni ipinlẹ Eko.

Wọn ti kede pe awọn ti ri oku eeyan meta yo bayii lara awọn eeyan to ha si abẹ ile naa.

Lọjọ Abameta ni ile naa dawo Ilé alájà mẹ́ta dàwó ní Yaba nílùú Eko, àwọn èèyàn há sábẹ́ rẹ̀ ni nkan bii aago meta lọsan ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii.

Wọn ti n kọ ile alaja mẹta naa lọ ki o to dawo, ni eyi ti enikankan ko tii le sọ houn to ṣokunfa bi ile naa ṣe dawo.

Ile to dawo ni Yaba
Àkọlé àwòrán, Ile to dawo ni Yaba

Igbese wo ni ipinle Eko ti gbe?

Yatọ si pe awọn ileeṣẹ ati ara adugbo ti n gbiyanju lati doola awọn to ha si abẹ ile alaja mẹta naa, Ijọba ipinlẹ Eko ni pe won ti fi ọwọ ofin mu ẹni to n kọ ile naa bayii.

Ẹrọ to n yọ nkan labẹ ilẹ naa ti n ṣiṣẹ nibẹ lati alẹ ana ti wọn ti gbe e de sibẹ.

Àkọlé fídíò, Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ