Ibadan Bullion Van Robbery: Ọ̀rẹ́ Mubarrak ní lóògbé san owó tó jẹ òun lọ́jọ́ tó kú torí ó ní òun lè má di ọ̀la

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Àdúrà pé kí Ọlọ́hun má jẹ̀ ẹ́ kí a rìn lọ́jọ́ tí ebi bá ń pa ọ̀nà, kí a má rin àrìnfẹsẹ̀sí, jẹ́ adura èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa ń gbà, tí wọ́n bá fẹ́ jáde nilè.
Ṣùgbọ́n ó jọ wí pé èyí kò rí bẹ̀ẹ̀ fún Mubarak Sulayman àti àwọn mẹ́ta mìíràn, tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè tó wáyé ní Idi-Ape, ìlú Ibadan lọ lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ kẹwàá, oṣù kejì, ọdún 2022.
Àṣìta ìbọn ló ba Mubarak Sulayman, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì níbi ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ọ̀hún.
- "Ìná tó ń ṣe àkóso ojú pópó ló dá ọkọ̀ agbówórìn dúró, tí adigunjalè fi kọ lù ú"
- Ọlọ́pàá kánkan kò ku sùgbọ́n a pa ọkan ninu àwọn tó fẹ́ já ọkọ̀ agbówórìn gbà-Ọlọ́pàá
- Ìyá Sunday Igboho wà lórí àìsàn torí kò rí ọmọ rẹ̀ - Agbekoya
- Davido, bá mi kọ ẹsẹ orin kan nínú àwo orin mi, jẹ́ ká da ayé láàmú - Portable Zazzu
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
- Mo fẹ́ ṣe ìyàwó pẹ̀lú ọmọọbabìnrin Ado Bayero ní Kano àmọ́ ń kò tíì mú ọjọ́ - Oluwo
Mubarak Sulayman, kó tó ṣe kòǹgẹ́ ọlọ́jọ́ rẹ̀, jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì "biomedical", olùkọ́ èdè Lárúbáwá àti atọ́nisọ́nà.
Ní ilé ẹ̀kọ́ fásitì Ibadan ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè kìíní àti ipò kejì.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlá, ọsù kejì ni wọ́n sin ín tí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ sì ń ṣe ìdárò rẹ̀.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ti sọ, Akinkunmi Akinpelu, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní, ó jọ pé Mubarak Sulayman ti mọ̀ pé òun yóò jáde láyé láìpẹ́.
Mubarak ti sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ:
Akinpelu ni lọ́jọ́ tí ó jáde láyé, ni Mubarak sọ fún òun pé kó jẹ́ kí òun san owó ohun tó rà lọ́wọ́ òun nítorí òun le má di ọ̀la, à fi bí ẹni pé òun yóò jáde láyé lọ́jọ́ náà gangan.
Ibrahim Ismail Ibrahim ní tirẹ̀ ikú Mubarak jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn ṣùgbọ́n kò sí ohun tí àwọn le ṣe fún Ọlọ́hun.
Bákan náà ni Waliyulah Olayiwola ní "ikú rẹ̀ bá mi lójijì, mo ti ń wa ẹkún mu, ó ṣòro fún mi láti gbàgbọ́ pé o ti jáde láyé.
"Lọ́jọ́ ọjọ́ keje, oṣù kejì la mọra ṣùgbọ́n níṣe ló dàbí pé a ti mọra fún ìgbà pípẹ́, tí a kò bá ríra, mo lè má mọ irú ènìyàn to jẹ́."

















