Olaiya Igwe: Àwọn ọmọde tí mò ń bá ṣe ‘skit’ ló dáwó jọ fún mi nígbà tí àìsàn inú dé sí mi

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Àwọn ọmọde tí mò ń bá ṣe ‘skit’ ló dáwó jọ fún mi nígbà tí àìsàn inú dé sí mi

Gbajugbaja osere tiata ni ede Yoruba, Ebun Oloyede ti ọpọ eeyan mọ si Igwe, ti salaye awọn ohun ti oju rẹ ri ninu ere tiata.

Nigba to n ba BBC Yoruba fi ọrọ jomitoro ọrọ, Igwe ni ọpọ nnkan ni oju oun ti ri, koda oun ti mu igbo ri laimọ.

Olaiya Igwe, ti ori sẹsẹ ko yọ lọwọ aisan okuta inu kindinrin to ba finra laipẹ yii wa salaye ipa ti awọn ọdọ to n ba se ere lori ayelujara ko lori iwosan rẹ.

Mo mu igbo ri laimọ:

Olaiya Igwe sọ fun BBC Yoruba ri pe wọn ti fun oun ni igbo jẹ ri lai mọ ohun ti oun jẹ afi igba to bẹrẹ isẹ ọwọ rẹ.

Osere tiata naa ni inu ere tiata kan ni oun ti sọ pe oun mu igbo lọ si orilẹede Ghana, ti oun si tun mu igbo pada, ti igbo naa ko si se ohunkohun fun oun.

O ni oun tun sọ pe oun ni oun maa n ba ti igbo jẹ, igbo ko le ba ti oun jẹ.

O ni ase ọrọ ti oun sọ yii ni awọn eeyan kan lagbo tiata yoo fi dan oun wo.

“A wa ninu gbọngan ayẹyẹ kan ni ọjọ kan, ara wa kan fun mi ni Bisikiiti pe ki n jẹ, mo si jẹ.

Ko pẹ ni gbogbo ibi ta joko si dabi igba ti wọn kọ ebe silẹ ni oju mi.

Mo wa n beere pe oko ibo la wa, ti wọn si ni inu Hall ni.”

Igwe ni ara oun ko lelẹ mọ, ti oun si ri pe oun ti j oun ti ko yẹ ki oun jẹ.

O ni se ni oun gba ile lọ lati sun lai le lọ si ibi ayẹyẹ ti wọn ti ni ki oun wa dari ere.

Awọn ọdọ ti mo n ba se ‘Skit‘ da owo jọ lasiko ti aisan inu de si mi:

Nigba to n fesi fun awọn eeyan to ni o maa n fi ara rẹ wọlẹ lati ba awọn ọdọ se ere tiata ranpẹ lori ayelujara eyi ti wọn n pe ni skit.

Olaiya Igwe ni ọpọ awọn ọdọ naa lo da owo jọ fun itọju oun nigba ti aisan inu n yọ oun lẹnu, oun ko si le fi ọrọ wọn sere.

O ni ọpọ awọn agbalagba ni ko ri oun nigba ti oun wa lori aisan amọ awọn ọdọ yii lo suru bo oun pẹlu owo fun itọju oun.

“Ida aadọrun ninu ọgọrun awọn ọdọ to n se ere tiata tabi lo ayelujara lo nifẹ mi, ti emi naa si nifẹ wọn.

Mo like ki n maa ba awọn ọmọde se skit, eyi to tun n ran emi naa lọwọ.

Awọn ọdọ tẹ n pe ni ọmọde yẹn, ero to n tẹle wọn lẹyin lori ayelujara ko kere rara, agbega lo jẹ fun mi ti mo ba ba wọn se ere.

N ko si kọ skit kankan ti wọn ba fun mi ri nitori aayo mi ni wọn.”

Ta ni Ebun Oloyede, to tun n jẹ Olaiya Igwe:

Ọmọ bibi ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Olaiya Igwe, ọjọ kẹtadinlogun osu keje si ni ọjọ ibi rẹ.

Alawada ati apanilẹrin ni Olaiya ninu ere tiata Yoruba, to si tun jẹ oludari ere.

O saba maa n ba awọn ọdọ se ere lori ayelujara, to si ti kopa ninu sinima ati fiimu agbelewo pẹlu.

Laipẹ yii lo se isẹ abẹ, ti wọn si yọ okuta nla to wa ninu kindinrin rẹ kuro.

Olaiya Igwe ti gba ọpọ ami ẹyẹ gẹgẹ bi osere tiata to dantọ.