Olaiya Igwe: Kò sí nnkan tó ṣe Ebun Oloyede, àlááfíà ló wà - Sokoti Alagbede

Oríṣun àwòrán, @olaiya_igwe01
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Adewale Abdulrasak Sokoti, ti ọpọ eeyan mọ si Sokoti Alagbede ti sọ pe ko ohunkohun to ṣe Ebun Oloyede ti ọpọ mọ si Olaiya Igwe.
Sokoti lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba lori iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri pe Olaiya Igwe ti jade laye.
O ni oun ati Olaiya ṣi foju ganni ara wọn laarin iṣẹju diẹ ki akọroyion BBC to kan si oun, alaafia si ni Olaiya wa.
- Àwọn ọmọ Sunday Igboho mẹ́jọ̀ nínú méjìlá níkan ní DSS gbé wá sí iléẹ̀jọ́ - Agbẹjọrò
- Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu mẹ́rin ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìwádìí Abba Kyari àti Ramoni Igbalode
- Micheal kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó lu ọlọ́kadà pa ní Abeokuta
- Rògbòdìyàn yóò bẹ́ sílẹ̀ láàrin Naijiria àti Benin tí wọ́n bá fi Sunday Igboho sílẹ̀ báyìí- Agbẹjọ́rò
- Ọta ìbọn ba ẹnìkan nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè àti ará ìlú kọjú ìjà síra wọn ní Yewa nípìnlẹ̀ Ogun
Sokoti sọ pe "Ẹ ma ka awọn to n sọ pe Olaiya ti ku si o, ko si nnkankan to ṣe Igwe."
"Mo n fi da yin loju pe Olaiya ko ku, alaafia lo wa, emi pẹlu rẹ ṣi sọrọ ni iṣẹju marun un sẹyin."

Oríṣun àwòrán, NaijaExpress.com
O tẹsiwaju pe "Mi o mọ nnkan to maa n ṣe awọn eeyan wa to jẹ pe ti wọn ba ti gbọ iroyin bayii, wọn kii fidi rẹ mulẹ ki wọn to maa pin irufẹ iroyin bẹẹ kiri."
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ gbode lọjọ Aje pe Olaiya Igwe ti jade laye nile iwosan ijọba apapọ to wa niluu Ibadan, UCH.
Iroyin naa ni Olaiya n ṣaisan kidirin, eyii to mu ẹmi rẹ lọ
Ebun Oloyede jẹ ọkan gboogi lara awọn oṣere tiata Yoruba ti irawọ wọn tan kaakiri orilẹ-ede Naijiria ati kaakiri agabye.
Lara awọn tiata ti Olaiya ti ṣe to milẹ titi ni Iru Esin, Ololade Mr Money, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- Àwọn jàndùkú kọlu Amuludun FM n'Ibadan, wọ́n ba ọ̀kẹ́ àìmoye dúkìá jẹ́
- Àwọn àgùnbánirọ̀ 25 lùgbàdì àrún Coronavirus ní ìpàgọ̀ NYSC
- Ta a ni ọ̀rẹ́ tóòtọ́, Ọba Buhari Oloto tó kú tó mú Ebenezer Obey wà nínú ìbànújẹ́?
- Ìdí rè é tí a ó fi gùnlẹ̀ ìyanṣẹ́lódí aláìlójọ́ káàkiri Naijiria - Ẹgbẹ́ Dokítà
- "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."













