Michael Salako and bike man death: Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú arákùnrin ẹní ogójì ọdún tó fí ìbínú lu Abudu ọlọ́kadà pa ní Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti ṣe afihan arakunrin kan to fi ibinu lu ọlọkada kan pa nitori pe o kọ lati gbe jade.
Micheal Salako la gbọ pe ọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa ti tẹ lagbegbe Lafenwa ni Abeokuta tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi ti ṣe sọ afurasi yi ti mọ ọlokada naa tipẹ nitori adugbo kan naa ni wọn jijọ n gbe.
- Rògbòdìyàn yóò bẹ́ sílẹ̀ láàrin Naijiria àti Benin tí wọ́n bá fi Sunday Igboho sílẹ̀ báyìí- Agbẹjọ́rò
- DPO ọlọ́pàá fi ọmọ odó lu èèyàn méjì pa, ó ṣe ẹnìkan lééṣe lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá
- Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án pa
- Alápatà lu ìyàwó rẹ̀ pa ní Ogun
- Awọn afurasí Babaláwo pa ìyáwó Ìmáàmù àgbà ìlú Ayere ní Kogi, Alayere dá sọ́rọ̀
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa "food poisoning" àti bí o ṣe lè dẹ́kun rẹ̀
- Fúnrara Bukola Saraki ló lọ sí EFCC láti lọ yanjú ọ̀rọ̀ ara rẹ̀- Agbẹnusọ Saraki
Abimbola sọ pe lẹyin tawọn gba ọrọ lẹnu rẹ, Micheal ni oun lọ beere lọwọ Abudu tii ṣe ọlọkada naa pe ki lo de to kọ lati gbe oun jade lana.
Nibi tawọn mejeeji ti n fa ọrọ naa ni ija ti bẹ silẹ ti Abudu si ṣubu lulẹ to si gba ibẹ di ero alakeji.
Alukoro ọlọpaa tẹsiwaju pe wọn ti gbe oku ọlọkada naa lọ si aaye igbe oku pamọ si ni mọṣuari lati le ṣayewọ lori ohun to ṣeku pa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣeleri lati ṣayẹwo ni kikun lori ohun to ṣokunfa iku Abudu ọlọkada naa.
- "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."
- N kò mọ̀ pé àsìkò yìí ni máa dágbéré fún Rachel Oniga- Jide Kosoko
- Èyí ni àlàyé lórí ètò ìsìnkú Tope AjogbaJesu àti ọjọ́ tí wọn yóò sin ín
- Ìdí rè é tí a ó fi gùnlẹ̀ ìyanṣẹ́lódí aláìlójọ́ káàkiri Naijiria - Ẹgbẹ́ Dokítà
- Ta a ni ọ̀rẹ́ tóòtọ́, Ọba Buhari Oloto tó kú tó mú Ebenezer Obey wà nínú ìbànújẹ́?
- Àwọn àgùnbánirọ̀ 25 lùgbàdì àrún Coronavirus ní ìpàgọ̀ NYSC
- Ọta ìbọn ba ẹnìkan nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè àti ará ìlú kọjú ìjà síra wọn ní Yewa nípìnlẹ̀ Ogun










