Tinubu death: Asiwaju ò kú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí nílé ìwòsàn ṣùgbọ́n kò sí ní Naijiria - Tunde Rahman

Oríṣun àwòrán, Tunde rahman
Agbẹnusọ eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, iyẹn Tunde Rahman ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin to sọ pe eekan oloṣelu naa ti jade laye.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Abamẹta, Rahman ni alaafia ni Tinubu wa bẹẹ ni ko ṣaisan kankan.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ni Tinubu ko ṣaisan, bẹẹ ni ko si ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun bi awọn eeyan kan ṣe n sọ.
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Rachel Oniga tó d'ágbére f'áyé
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá, ẹ ríi dájú pé ẹ tú gbogbo àṣírí nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Abba Kyari àti Hushpuppi - Àpapọ̀ Agbẹjọ́rọ̀
- Èyí ni àlàyé lórí ètò ìsìnkú Tope AjogbaJesu àti ọjọ́ tí wọn yóò sin ín
- 'Hàá, irú ikú tí ọmọ mí kú kò tọ́ síi, aláànú mí ní'
- Àfìgbà tóò dúró ká jọ gbé orin tuntun wa pẹ̀lú Alhaji Mustapha Abiola jáde - Ẹnìkejì Tope Ajogbajesu
O ni "Asiwaju Bola Tinubu ko ṣaisan, bẹẹ ni ko si nile iwosan nitori ko ṣe ailera ti yoo mu ko dero ile iwosan."
Rahman sọ pe lootọ ni eekan ẹgbẹ oṣelu APC ọhun ko si ni Naijiria lọwọ yii, ṣugbọn yoo pada wa si Naijiria laipẹ jọjọ.
O tẹsiwaju pe "Gbogbo igba ti Tinubu ba ti tẹkọ leti lọ silẹ okeere ni awọn kọlọrọsi kan maa n sọ pe o ti dubulẹ aisan tabi pe o ti jade laye."
"O ṣeni laanu pe ni gbogbo igba ti wọn ba ti n gbe ahesọ iroyin bẹẹ , otitọ ṣi maa n jade pe irọ ni wọn n pa sibẹ, wọn kọ lati jawọ."
Rahman pari ọrọ rẹ pe ọwọ Ọlọrun ni ẹmi gbogbo eeyan wa, niroti naa ko si ẹni to le sọ igba ti ẹnikẹni yoo fi aye silẹ ayafi adaniwaye nikan.
Bi ẹ ko ba gbagbe, kii ṣe igba akọkọ ree ti iroyin yoo gbode kan pe gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa ti jade laye ṣugbọn ti ọrọ ko ri bẹẹ.
- Ìrètí Nàìjíríà bọ́ sómi! Ògùn olóró líló mú kí AIU lé Blessing Okagbare kúrò ní Tokyo 2020 Olympics
- Àwọn ohun mẹ́rin tó yẹ kí ẹ ko mọ nípa Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
- 'Nàiìjíríà ti pèsè ''Private jet'' tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀'
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ẹgbẹ́ illuminati lè sọ èèyàn di olówó? Ohun méjìlá tí a mọ̀ rèé
- 'Ẹgbẹ́ APC ẹ funra, "Oríyọmí" lásán ni Akeredolu fí na Jegede mọ́lẹ̀ ní iléẹjó tó gajù lọ'














