Illumminati: Ìbéèrè méjìlá tó yẹ kóo mọ̀ nípa ẹgbẹ́ Illuminati

Aworan Illuminati

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn miran ni ẹgbẹ okunkun to fẹ gba gbogbo aye kan ni Illuminati, ti wọn si wa lẹyin ọpọlọpọ ipaniyan ati awọn ohun miran.

Amọ lakọkọ, Iluminati jẹ orukọ ti wọn fun ileeṣẹ kan to n ri si kara-kata ilẹ ati ile, ti wọn da silẹ ni nkan bi igba ọdun o le marundinlaadọta sẹyin labẹ ileeṣẹ Shell.

Amọ orisirisi iroyin ni o wa lori ayelujara nipa ẹgbẹ yii, lai si aridaju to peye.

Awọn miran ni ẹgbẹ okunkun to fẹ gba gbogbo aye kan ni, ti wọn si wa lẹyin ọpọlọpọ ipaniyan ati awọn ohun miran.

Amọ ohun ti a mọ nipa ẹgbẹ Iluminati naa ni yii?

  • Awọn wo ni iIluminati?

Ẹgbẹ okunkun ni ẹgbẹ ti wọn n pe ni ''The Order of Iluminati'' ti wọn da silẹ ni Bavaria, ni ọdun 1776 si ọdun 1785 ni agbegbe to wa lorilẹede Germany ni aye ode oni.

  • Ẹni to da ẹgbẹ naa silẹ ni Adam Weishaupt to fẹ ki ẹgbẹ naa dagba nipa ọrọ eto ẹkọ, imọ Philososophy amọ ko niiṣe pẹlu eto ẹsin kankan, ti ẹyẹ owiwi si jẹ ami idanimọ ẹgbẹ wọn
Emblème des Illuminati de Bavière
Àkọlé àwòrán, Emblème des Illuminati de Bavière
  • Awọn eniyan ma n da ẹgbẹ okunkun Freemasons pọ mọ Iluminati, amọ wọn kii ṣe nkankan naa nitori awọn ẹlẹgbẹ okunkun Iluminati lo ma n fa awọn Freemasons ti wọn jẹ akọle wọ inu ẹgbẹ wọn, amọ nitori ibaṣepọ to wa laaarin wọn ni awọn eniyan fi ma n gbe wọn si ara wọn.
Àkọlé fídíò, Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Mi ò gbè lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ mo wà lẹ́yìn Sunday Igb
  • Bawo ni wọn ṣe n darapọ mọ ẹgbẹ illuminati?

O gbọdọ ni atilẹyin gbogbo ọmọ ẹgbẹ to ku, o gbọdọ jẹ ọlọla ati gbajumọ ni awujọ ati laarin ẹbi. Bakan naa ni idagbasoke ninu ẹgbẹ naa jẹ ṣiṣẹ n tele.

Owo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Ṣe lootọ ni awọn ẹgbẹ illuminati n ṣe ẹbọ ati etutu?

Lootọ ni wọn n ṣe ẹbọ, amọ ko han si gbangba, wọn si ma n lo orukọ idakọnko lati maṣe jẹ ki eniyan mọ awọn to wa ninu ẹgbẹ wọn.

  • Bi awọn eniyan ṣe n goke ninu ẹgbẹ naa ni lati kọ akọsilẹ nipa awọn iwe ti wọn ni, iru ipenija ti wọn n doju kọ, orukọ awọn ọta wọn ati ileri pe ifẹ ara wọn ko ni kọja ifẹ ti wọn ni si ẹgbẹ naa.
Àkọlé fídíò, Se lootọ?: Wo irú sítàílì tó yẹ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìbàlópọ̀ lẹ́yìn ìbímọ- Tola Ajayi
  • Ẹyinju to jẹ asia ẹgbẹ wọn ''Eye of Providence'' lo wa lara awọn ile ijọsin, banki ati awọn ile lorilẹede Amẹrika, eleyii to sapejuwe bi awọn ọmọ ẹgbẹ yii ṣe n mọ nipa ohun gbogbo to n ṣẹlẹ ni agbaye.Amọ, awọn ẹlẹsin Kristẹni to n lo asia oju yii tẹlẹ lati sapejuwe titobi Ọlọrun ni gbogbo aye.
Owo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Ṣe lootọ ni illuminati ti gba isakoso aye? Awọn miran gbagbọ pe lootọ ni ẹgbẹ yii lo n dari ohun gbogbo to n ṣẹlẹ ni aye, amọ awọn onimọ gbagbo wi pe awọn ẹgbẹ iluminati nigba ti wọn kọkọ da silẹ ko lagbara pupo lori gbogbo ẹka lagbaye.
  • Njẹ ilumọọka kankan wa ni Illuminati? Ni ọdun 1782, eniyan ẹgbẹta lo wa ninu ẹgbẹ naa ti arakunrin ilumọọka lati orilẹede Germany, Baron Adolph Von Knigge si wa ni ara wọn, ti wọn si to ẹgbẹrun meji si mẹta ni nkan bi ọdun 1784.
Johann Adam Weishaupt (1748-1830)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Johann Adam Weishaupt lo bẹrẹ illuminati
  • Ki lo de ti wọn ko gburo illuminati mọ? Ọdun 1784 ni ọba ilẹ Bavaria fi ofin de ki ileeṣẹ kankan ni ibaṣepọ pẹlu iluminati, to si gbe aṣẹ kalẹ to fofin de apejọpọ ẹgbẹ naa, pẹlu igbagbọ wi pe ẹgbẹ iluminati naa n ṣe atilẹyin fun ki awọn eniyan jẹri pe ko si Ọlọrun abi ki wọn ma a gba ẹmi ara wọn, eleyii to lodi si ofin ẹsin Kristẹni.
Àkọlé fídíò, Funmi Aragbaiye: Ọlọ́run ní ohun táwọn olórí wa fẹ́ jẹ ni wọn ń wá
  • Ki lo de ti awọn eniyan ṣi n sọrọ illuminati di oni? Lẹyin ti wọn tu wọn ka ni ọpọlọpọ iroyin nipa wọn bẹrẹ si ni jade , ti awọn eniyan si n sọ ohun ti wọn mọ, pe awọn lo da ogun ''French Revolution'' silẹ.Lẹyin igba naa ni awọn onkọwe woye pe ẹgbẹ okunkun naa ṣi wa ati pe aarẹ kẹta ilẹ Amerika, Thomas Jefferson wa lara wọn.
  • Bakan naa ni titi di oni awọn kan si gbagbọ wi pe Iluminati n sakoso lagbaye nitori awọn olorin igbalode, awọn aarẹ lorilẹede Amerika to fi mọ Beyoncé ati Jay-Z ni iroyin gbe pe wọn wa ninu ẹgbẹ okunkun naa, amọ wọn ni ko si ohun to jọ ọ.