Mayowa Omoniyi: Olùkọ́ rẹ̀ ní òun ni atagìtá ''Hawaiian guitar'' tó kéré jùlọ lágbàáyé

Àkọlé fídíò, Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

Omo ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samu samu.

Bẹẹ ni ọrọ Mayowa Omoniyi jẹ, ọmọ ọdun mẹtala to pegede ju agbalagba miran lọ ninu gita tita.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Mayowa ni baba oun lo kọ oun bi wọn se n ta jita, bakan naa si ni oun le tẹ duuru pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ko si orin Ebenezer Obey, Sunny Ade, takansufe tabi orin ẹmi ti oun ko le tẹ jita si gẹgẹ bii akọsẹmọsẹ atajita.

Nigba tawọn naa n sọrọ nipa bi Mayowa ti dangajia si ninu jita tita, Taiwo Omoniyi, tii se baba Mayowa ati ibeji rẹ, Kehinde fidi rẹ mulẹ pe Mayowa ti kọja ipo tawọn wa ninu jita tita.

Bakan naa ni olukọ to n kọ Mayowa ni ohun elo orin, Samson Akinola ni iwadi oun fihan pe lọwọ lọwọ bayii, Mayowa Omoniyi ni atajita to kere julọ lagbayee.

O ni ko si irufẹ orin ti Mayowa ko le ta jita si.