Seriki Williams Abass: Ọba Badagry tó jẹ́ ẹrú, tó tún padà di olówò ẹrú

Ọba Seriki Ifaremilekun Williams Abass Fagbemi

Oríṣun àwòrán, Others

Arise ni arika, arika si ni baba iregun, ọpọ ohun ti a ba se ni oni, n bọ wa di itan to ba di ọla.

Idi ree ti iran Yoruba ko fi lee gbagbe ipa manigbagbe ti Ọba Seriki Ifaremilekun Williams Abass Fagbemi se nigba aye rẹ.

O si daju pe bi onirese ko ba fin igba mọ, eyi to ti fin silẹ ko lee parun mọ laelae.

Alaye si ree lori bi Ọba Seriki Abass se lo igbe aye rẹ gẹgẹ baa se ka a loju opo Wikipedia ati awọn oju opo itakun agbaye miran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Itan aye Ọba Seriki Ifaremilekun Abass Williams Fagbemi:

Abule Joga-Orile lagbegbe ilu Ilaro nipinlẹ Ogun bayii ni wọn ti bi Ifaremilekun, ti orukọ baba rẹ si n jẹ Fagbemi.

Olowo ẹru kan nilu Dahomey ti orukọ rẹ n jẹ Abass si lo mu lẹru lasiko ogun Dahomey ati Egba nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹfa, to si pa orukọ rẹ da si ti ọga rẹ.

Brazillian Barracoon

Oríṣun àwòrán, Others

Idi si ree to fi n jẹ Ifaremilẹkun Fagbemi Abass.

Lẹyin naa ni wọn ta a soko ẹru fun oyinbo Brazil kan to n jẹ Williams, ẹni to gbe Seriki Abass lọ sorilẹ-ede Brazil lati lọ se ọmọ ọdọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Emeritus Ayo Bamgbose: Ibánújẹ́ ni ojú yẹpẹrẹ tí ìjọba fi n wo olùkọ́ báyìí jẹ́ fún mi

Ni kete to si de silẹ Brazil ni ọga rẹ yii tun yi orukọ rẹ pada si Williams nitori ẹru ko ni idamọ kankan to yatọ si ti olowo rẹ.

Brazil ni William Abass ti mọọkọ-mọọka ninu ede Dutch tilẹ Netherlands, bakan naa lo gbọ ede Geesi, Spanish ati Pọtugi.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Nigba to ya ni Seriki Abass pada sorilẹ-ede Naijiria lẹyin to ti se adehun pẹlu ọga rẹ, Williams pe oun yoo jẹ alabasisẹpọ rẹ ninu owo ẹru.

Agbegbe Ọfin ni isalẹ Eko nilu Eko ni William Abass tẹdo si nigba to ti orilẹ-ede Portugal de, ti ọpọ arọmọdọmọ rẹ to wa nisalẹ Eko lonii si n jẹ Williams, nigba tawọn miran pa orukọ mejeeji pọ, William Abass.

Iboji Ọba Seriki Ifaremilekun Williams Abass Fagbemi

Oríṣun àwòrán, Others

Lẹyin naa lo tun lọ tẹdo silu Badagry laarin ọdun 1830, nibiti owo ẹru ti gbilẹ, to si mọ ilu naa bii atẹlẹwọ rẹ nitori o sunmọ ilu Porto Novo to ti se ẹru tẹlẹ.

William Abass n sisẹ owo ẹru lọ pẹlu ọga rẹ ni Brazil, to si n fi ọpọ ẹrun ransẹ si onitọun, ti oun naa si n ni owo ati ọrọ lati ipasẹ okoowo ẹru naa.

Pẹlu atilẹyin ọga rẹ, William Abass kọ ibudo nla kan silu Badagry ti wọn pe ni Brazillian Barracoon eyi ti wọn kọkọ fi ọparun kọ lọdun 1840.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Lẹyin eyi ni wọn wa fi biriki, iso ati paanu kọ ile naa eyi ti wọn ko wa lati oke okun, nibiti wọn n ko ọpọ ẹru pamọ si, eyi to wa nilu Badagry di oni olonii.

William Abass di eekan ilu nilu Badagry, nigba ti yoo si fi di ọdun 1895, ọla ati owo rẹ ti burẹkẹ debi pe awujọ awọn Musulumi fi jẹ oye Seriki Musulumi fun ilẹ Yoruba lọdun 1895.

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase

Nigba to ya ni awọn eebo amunisin fi jẹ ọba ilu Badagry lọdun 1913, ẹni to ba si de ile rẹ naa nilu Badagry, yoo ri aloku awọn ohun to fi n se ọla lasiko naa.

Lẹyin eyi ni Ọba Seriki Abass Williams tun da awọn ilu meji miran silẹ nilẹ Yoruba, awọn ilu naa ni Ayetoro ati Idogo, ti wọn wa nipinilẹ Ogun titi di oni.

Ọba Seriki Abass Williams lọla, o lowo, ti akọsilẹ kan si sọ pe o ni aya toto mejidinlaadoje pẹlu ọmọ mẹrinlelogoje.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Ọpọ aseyọri ni Ọba Seriki Abass Williams se lasiko to wa lori loke eepẹ, lara wọn si ree:

Aseyọri Ọba Seriki Abass Williams:

  • O pin erekusu Gerefu si wẹwẹẹ lọdun 1882
  • Oyinbo amunisin, ọgagun J.E Ewart fi Ọba Seriki Abass Williams se olori oselu ilu Badagry lọdun 1895
Àkọlé fídíò, Badagry: Ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú tó ń lọ sókè òkun
  • Ọdun 1895 yii naa ni awujọ Musulumi fi jẹ Seriki ilẹ Yoruba, to si kọ Mọsalasi nla to wa ni Sango nilu Badagry lọdun 1896
  • Ọdun 1899 lo da ẹgbẹ Kila silẹ, to si ko awọn Musulumi jọ lati kọwe ẹhonu si adele gomina Denton pe ko da ileẹkọ silẹ fawọn Musulumi nilu Badagry
  • Ọba Seriki Abass Williams di aarẹ fun kootu ibilẹ nilu Ilaro, Addo, Idogo, Igbeda, Oke Odan, Eggua Ipokia, Leke ati bẹẹ bẹẹ lọ
Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'
  • Ọba Seriki Abass Williams ni aarẹ fun gbogbo ẹkun Ilaro, to si maa n gbe ade le awọn Alase tilu Ilase ati Oniboro tilu Iboro lori

Ọjọ Kọkanla, osu Kẹfa, ọdun 1919 ni Ọba Seriki Ifaremilekun Abass Williams Fagbemi waja nilu Badagry.

Wọn sin sinu agboole rẹ ti wọn n pe ni Brazillian Barracoon nilana ẹsin Musulumi.

Brazillian Barracoon

Oríṣun àwòrán, Others

Itan ti igbe aye Ọba Seriki Abass Williams kọ wa:

Itan aye Ọba Seriki Abass Williams kọ wa lati lu aluyọ lai naani bi ibẹrẹ aye wa se ri

O tun kọ wa lati jẹ olotitọ si awọn eeyan to jẹ asiwaju si wa boya ọga wa lẹnu isẹ abi obi wa

Itan yii tun kọ wa pe ka maa ranti ile ni orilẹ-ede korilẹ-ede ta a ba wa.

Àkọlé fídíò, 'Tíátà ọ́mọdé tí wọ́n ń kọ́ wa ní Bariga ti mú mi lọ Germany, Switzerland, Amsterdam...'