Agbekoya War: Ọta ìbọn kan ṣoṣo ló fa ogun tó fi ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò nínú ìtàn mánigbàgbé lẹ̀ Yorùbá

Agbekoya

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ogun Agbekoya

Yoruba ni ogun ko dabi iyan, ogun ko ri bii ẹkọ, ẹni ti yoo si royin ogun, ko ni ku.

Ọpọ ogun lo ti waye ṣẹyin nilẹ Yoruba, eyi ti ko lonka amọ manigbagbe nla ni ogun Agbekoya jẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe ka a loju opo Wikipedia atawọn oju opo miran lori ayelujara, ọta ìbọn kan ṣoṣo lo sokunfa ogun Agbekoya, eyi to mu ọpọ ẹmi lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi ogun naa si ṣe jẹ manigbagbe lo mu ka ṣe akojọpọ awọn koko nnkan pataki to yẹ kẹ mọ nipa ogun naa.

Koko ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa ogun Agbekoya:

Aarin ọdun 1968 si 1969 ni ogun Agbekoya waye laarin awọn agbẹ ati ijọba ẹkun Iwọ oorun Naijiria ijọhun.

Ogun yii ṣe pataki nitori pe ohun ni ogun akọkọ yika Naijiria ninu eyi tawọn mẹkunnu to jẹ agbẹ, ti kọju oro sijọba.

Ọrọ owo ori sisan si lo fa ogun naa, bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan lero pe o tun lọwọ ọrọ oselu diẹ ninu.

Agbekoya

Oríṣun àwòrán, others

Laarin ọdun 1950, ijọba amunisin to n dari Naijiria nigba naa ṣe agbekalẹ ibudo ti wọn n ko eso kòkó, tijọba ba ra lọwọ awọn agbẹ, pamọ si.

Bakan naa ni ẹgbẹ alafọwọsowọpọ fawọn agbẹ wa, to maa n duna-dura laarin agbẹ ati ìjọba lori iye owo koko.

Lasiko yii ni ijọba ẹkun ìwọ oorun Naijiria to jẹ ẹya Yoruba, pinnu lati fi owo kun owo ori awọn agbẹ.

Ẹgbẹ alajẹsẹku yii si ni ijọba gbọkan le lati lo fun gbigba afikun owo ori naa.

Nigba to di ọdun 1968 ti wahala naa yoo bẹrẹ, ogun abẹle ti n waye lọwọ ni Naijiria, ohun gbogbo ko ṣe deede mọ

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Koda, ọpọ osisẹ to n soju ijọba lo ti n gba riba, ti wọn si n mu ara ní araalu, paapaa awọn agbẹ.

Ọna lati gba ara wọn silẹ lọwọ ijẹgaba ati ifiyajẹni yii, lo mu ki awọn agbẹ korajọpọ bii ẹlẹgbẹjẹgbẹ, eyi ti wọn sọ ni Agbekoya.

Ọpọ ikunsinu lo n waye laarin awọn agbẹ yii atawọn asoju ijọba to n yẹ koko wo nitori ayẹwo ati osunwọn eke pẹlu eru ti wọn n ṣe nidi koko.

Bẹẹ ni owo tasọrẹ ti ko gbe iwọn koko ti awọn agbẹ ko silẹ, ni ijọba n san fun wọn, eyi to n fa ikunsinu labẹlẹ.

Àkọlé fídíò, The Polytechnic Ibadan: Ẹ̀rọ abẹ́lé tó ń fọ ọwọ́ àti ‘Ventilator’ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

Bakan naa ni owo ori ti wọn n san ko ṣe ọgbọọgba lati ọdọ agbẹ kan si ekeji, ti katakara oko-owo koko si n ṣe sege sege.

Lẹyin o rẹyin, ijọba gbe owo gun owo ori tawọn agbẹ yoo maa san si dọla mẹjọ ($8) dipo dọla kan ati sílè mẹwa ($1.10,) tawọn agbẹ fẹ san.

Igbesẹ naa ko dun mọ awọn agbẹ ninu rara, ti wọn si n wọna bi wọn yoo ṣe bọ lọwọ ajaga ijọba naa.

Bi ogun Agbekoya ṣe lọ:

Awọn agbẹ ko ara wọn jọ lati tako ijọba ọgagun Adeyinka Adebayo to n dari ẹkùn Iwọ oorun guusu Naijiria nigba naa nitori ele gọbọi to gun owo ori naa.

Ijọba fọn awọn ọlọpaa da sita lati ṣẹ eegun awọn agbẹ naa, bẹẹ si ni gbogbo ẹbẹ tawọn agbẹ ṣe sijọba lati ipasẹ awọn eekan ilu, lo ja si pabo.

Lara awọn asaaju ẹgbẹ Agbekoya nigba naa ni, Tafa Adeoye, Folarin Idowu, Mustafa Okikirungbo, Tafa Popoola, Adeniyi Eda, Adeagbo Kobiowu, Rafiu Isola, Adegoke Akekuejo ati Mudasiru Adeniran.

Awọn agbẹ yii bẹrẹ si ṣe iwọde yika aba kọọkan, ti wọn si n kọrin "Ọ̀kẹ́ mẹfa la o san", eyi tii ṣe ọgbọn ṣílè.

Àkọlé fídíò, Teach your children Yoruba: Wo àwọn òyìnbó tó ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní Michigan, America

Bi wọn si ṣe n ṣe ẹhonu kọrin kiri aba kọọkan, ni wọn tun n ṣe ikilọ fawọn agbẹ akẹẹgbẹ wọn pe, wọn ko gbọdọ san owo ori kankan fun ijọba.

Nigba to ya, wọn gbe ẹhonu wọn lọ soke Mapo, níbi ti Ileesẹ ijọba wa nigba naa, tí wọn si da gbogbo ọọfisi ijọba ru.

Ọna lati dẹkun rigbodiyan to le ti idi ẹhonu yii suyọ, lo mu ki ijọba lo iwa ipa lati bomi pana rẹ, ti wọn si ti awọn asaaju ẹgbẹ Agbekoya kan mọle.

Igbesẹ ijọba naa bọ si apo ibinu awọn agbẹ, ti wọn si n ba dukia ijọba jẹ, bẹẹni wọn pa ọpọ oṣiṣẹ ijọba, ti ohun gbogbo si tun dojude ni ẹkun ìwọ oorun guusu Naijiria lasiko ti ogun abẹle n lọ lọwọ.

Lara awọn dukia ijọba tawọn agbẹ naa bajẹ ni ọpọ ile ẹjọ ati ile ijọba, ti wọn si tun tu ọpọlọpọ ẹlẹwọn silẹ, to fi mọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Nigba to di ọjọ kinni, osu keje, awọn ọlọpaa ya bo awọn agbẹ ni Olorunda, lẹba Akanran nilu Ibadan, ti wọn si n kọrin pe awọn yoo fi oju awọn agbẹ naa ri mabo.

Asiko yii si ni awọn agbẹ lọ duro de wọn ni Olorunda, ti wọn ko si ṣe ohunkohun sáwọn ọlọpaa naa nitori wọn n duro de asaaju wọn, Tafa Adeoye, ko de gẹgẹ bii adehun wọn.

Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọlọpaa naa fa ìbọn yọ, to si yin in si meji lara awọn Agbekoya naa, ti awọn yoku si na papa bora nitori wọn ko fẹ ki wahala sẹlẹ ki Tafa Adeoye to de.

Ọkan lara awọn to ja ninu ogun Agbekoya, Alhaji Lalekan Lasisi Akekaka, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu awọn akọroyin salaye pe, bi iroyin ṣe kan Tafa Adeoye ni Akanran lo sare wa si Olorunda lati Akanran, lati mọ ohun to n sẹlẹ.

Agbekoya

Oríṣun àwòrán, others

Iroyin ni: "Bo si ṣe rí oku agbẹ meji nilẹ ni Tafa Adeoye tarapooro pe, ṣe awọn eeyan yii wa ba wa ja ni?"

Akekaka ni Tafa gba ìbon lọwọ ọkan lara awọn agbẹ, to si yin in si ọkan lara awọn ọlọpaa naa, eyi to jẹ ọta ìbọn kan ṣoṣo to bẹrẹ ogun Agbekoya.

Ọpọlọpọ ẹmi ọlọpaa ati agbẹ pẹlu araalu lo si bọ sinu ogun Agbekoya naa, eyi to waye nitori ele owo ori lasan lasan.

Ija ti a sọ wẹrẹ yii le ni ọdun kan to fi waye, ti iroyin atẹnu-dẹnu kan si ni ọgbọn ẹwẹ ni ọlọpaa obinrin kan fi mu Tafa Adeoye.

Iroyin naa ni obinrin ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ọhun lo fẹ baba yii bii ọkọ, lati ri idi agbara rẹ, eyi to mu ko rọrun lẹyin o rẹyìn lati mu Tafa Adeoye, lẹyin ti ogun naa wa sopin.

Àkọlé fídíò, Victor Agunbiade ni ojú àlá ni Ọlọrun ti yan iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi fún òun ní America

Ṣugbọn ibeere ọpọ eeyan lẹyin ogun Agbekoya naa ni pe, ṣe ominira wa de fun awọn agbẹ naa titi di akoko ta wa yii abi wọn kan fi ẹmi ọpọ eeyan sofo lasan?

Ipari ogun Agbekoya ati ipẹyinda rẹ:

Lẹyin o rẹyin, ogun Agbekoya wa sopin ni kete ti wọn tu Oloye Obafemi Awolowo silẹ lọgba ẹwọn, to si pẹtu si awọn agbẹ lati bomi suuru mu.

Bakan naa ni Awolowo ba awọn Agbekoya dunadura lori fanfa to wa laarin wọn ati ijọba, ti wọn si sọ ohun ti wọn n fẹ fun.

Lẹyin ipẹtu saawọ ati idunadura naa, ijọba le awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ to n ṣe akoso abule kọọkan kuro, to fi mọ awọn Bàálẹ́.

Bakan naa ni adinku ba owo ori to fa laasigbo naa, tijọba si tun pinnu lati mase lo awọn afipa gba owo ori mọ.

Àkọlé fídíò, Risikat Moromoke Azeez: Inú èmí àti Òbí mi dùn nígbà ti Risi bí ọmọ olójú búlù- Wasiu

Ko tan sibẹ o, ele tun ba owo tijọba n ra koko lọwọ awọn agbẹ, to si tun ṣe atunṣe awọn oju popo to wọ abule kọọkan.

Ẹkọ to wa lara ogun Agbekoya:

  • Ẹkọ akọkọ ta ri kọ lati ara ogun Agbekoya ni pe, ifikunlukun, asọyepọ ati idunadura ṣe pataki ju ogun jija lọ nitori nigbẹyin ogun, wọn yoo pada joko yanju aawọ naa ni.
  • Ẹkọ kejì ni pe, o yẹ ki awọn agbofinro wa maa fi pẹlẹ putu huwa si araalu, ko dara to ki wọn maa sare yin ìbọn pa eeyan, eyi to le fa rogbodiyan.
  • Ẹkọ kẹta naa ni pe, ki araalu maa fi suuru huwa lasiko ti iṣẹlẹ kan ba n gbona lara wọn, ko si yẹ ki wọn maa ba dukia ijọba jẹ.
  • Ẹkọ kẹrin ni pe, ki awọn oṣiṣẹ ijọba dẹkun riba gbigba, ki wọn si ṣe iṣẹ wọn lai fi ele ti yoo lọ sapo wọn kun un owo ti wọn n gba lọwọ araalu nitori eyi lee tun bi idarudapọ lọwọ iwaju.