Funmi Aragbaiye: Ọlọ́run ní ohun táwọn olórí wa fẹ́ jẹ ni wọn ń wá ni ìlú kò fi rọgbọ

Àkọlé fídíò, Funmi Aragbaiye: Ọlọ́run ní ohun táwọn olórí wa fẹ́ jẹ ni wọn ń wá

Ilumọọka akọrin ẹmi nni, Funmi Aragbaiye ti kede pe ọjọ ti pẹ ti Ọlọrun ti fi iran han oun nipa idasilẹ orilẹede Yoruba.

Aragbaiye, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe Ọlọrun sọ fun oun ninu ẹmi pe aisi isọkan laarin iran Yoruba le mu ifasẹyin wa lori idasilẹ orilẹede wọn.

O ni idi ree ti oun se gbe awo orin kan sita nigba naa lati parọwa si iran Yoruba pe ki wọn se ara wọn ni ọkan soso.

Akọrin ẹmi naa tun woye pe ohun ko ri iru asiko ti ilu yoo le bayii ri lati igba ti oun ti de ile aye, eyi to ni ko sẹyin awọn asaaju ilẹ wa ti ko dara.

O fikun pe aye ologun la n pariwo pe ko dara laimọ pe akoko ti yoo buru si wa niwaju lasiko ti oun fi orin ẹmi se isipaya fawọn eeyan ni bii ọgbọn ọdun sẹyin.

O wa salaye pe gbogbo ọmọ Naijiria la ti sẹ, ti iya yii fi pọ, awa si ni ko jẹ ki adura gba lori orilẹede yii.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajihinrere naa wa woye pe nnkan ko le pada si bo se wa sẹyin mọ ayafi ka maa bẹ Ọlọrun ko mu igba dẹ wa lọrun pada ni.