Ìtàn mánigbàgbé: J.F Odunjo kó ipa ribiribi sí àgbéga èdè Yorùbá

JF Odunjo

Oríṣun àwòrán, JF Odunjo

Ta ba n sọrọ nipa awọn onkọwe nilẹ Yoruba, a ko lee ka orukọ wọn lai ma fi orukọ Joseph Folahan Odunjo si aarin wọn nitori odu ni, kii se aimọ laarin awọn oloko onkọwe.

Ta ba si ni ka maa darukọ awọn to jẹ sawawu oloogbe Odunjọ, a o mẹnuba Daniel Olorunfẹmi Fagunwa, taa mọ si D.O Fagunwa, ẹni ti oun naa se gudugudu meje ati ya ya ya mẹfa ninu isẹ iwe itan arokọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ wa lo ka iwe onkọwe yii lasiko taa wa nile iwe, bẹẹ si ni bi onirese J.F Odunjo ko ba fingba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ ko lee parun laelae.

Idi si ree ti BBC Yoruba fi fẹ ka mọ nipa itan igbe aye akọni onkọtan naa.

ITAN IGBE AYE J.F ODUNJO GẸGẸ BO ṢE WA LOJU OPO ITAKUN AGBAYE:

  • Joseph Folahan Odunjo de ile aye lọdun 1904, to si fori sọlẹ si agbegbe Ibara nilu Abẹokuta
  • J.F Odunjo lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ St Augustine to wa nilu Abẹokuta, ko to gba ile ẹkọ girama ti ijọ Aguda lọ, eyiun Catholic Higher Elementary Training School
  • Lẹyin eyi ni J.F Odunjo morile ilu London lati lọ sile ẹkọ olukọni kan nibẹ
  • Laarin ọdun 1924 si 1927 ni J.F Odunjo fi sisẹ olukọ nilu Ibadan, ko to wa lọ di ọga agba fun ileẹkọ alakọbẹrẹ to lọ, eyiun St Augustines
  • Bakan naa lo si tun sisẹ olukọ lawọn ileẹkọ ijọ Aguda lorisirisi laarin ọdun 1940 si 1950, ko to maa kọ iwe taa mọ ọ mọ
  • J.F Odunjo kọ awọn iwe akagbadun, arosọ, ere onise, ewi, ati iwe kika ni ede Yoruba pọnbele, ti awọn iwe yii si di ohun iwuri ati itọni fun ọpọ onkọwe ode oni
Àkọlé fídíò, Wo itan omi gbigbona ati tutu ni Ikọgosi Ekiti
  • Bakan naa ni akọni onkọwe yii wa lara awọn ọmọ igbimọ to n risi akọtọ ede Yoruba (Yoruba Orthography Committees) laarin ọdun 1966 si 1969
  • Lara awọn iwe ti J.F Odunjo kọ ni Isẹ ni oogun isẹ, Tọju iwa rẹ ọrẹ mi ati akojọpọ ewi aladun, Ọmọ bẹẹrẹ, osi bẹẹrẹ, Owo Apekanuko, eyi ti gbogbo wọn jẹ ewi to gbe jade lọdun 1961
  • Lẹyin naa lo kọ awọn Alawiye Yoruba akọkọ fun awọn ọmọde nile ẹkọ alakọbẹrẹ lọdun 1943, eyi to gbajugbaja pupọ di oni
  • Ọdun 1964 ni J.F Odunjo kọ iwe Ọmọ oku ọrun, to si kọ iwe Kuyẹ lọdun 1978
  • J.F Odunjo tun jẹ ọmọ ẹgbẹ olukọ nilẹ wa Naijiria fun ọpọlọpọ ọdun, o jẹ akọwe ẹgbẹ naa laarin ọdun 1942 si 1951.
  • O si tun jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilẹ Ẹgbado, taa mọ si Yewa bayii, ẹka ti Eko ni ọdun 1941 si 1951
  • Lọdun 1951, J.F Odunjo dibo, to si wọle sile asofin lẹkun iwọ oorun Naijiria, lẹyin naa ni wọn tun yan an gẹgẹ bii Minisita fọrọ ilẹ ati osisẹ
  • J.F Odunjo ni Asiwaju ilẹ Ẹgba, ko to dagbere fun aye pe o digbose lọdun 1980.
Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Oloogbe Oloye Joseph Folahan Odunjo jẹ eeyan nla, ẹni takuntakun to ko ipa tiẹ, ti kii se keremi si ilọsiwaju ede Yoruba ati isẹ olukọ nilẹ Yoruba.

Titi laelae si la o maa ranti akọni onkọwe naa fun ipa ribiribi to ko si ede Yoruba, bi o tilẹ jẹ pe J.F Odunjo ti ku, amọ isẹ ọwọ rẹ si n fọhun sibẹ, ti iran Yoruba ko si le gbagbe rẹ titi aye.

A wa n gbadura pe ki Ọba oke tẹ Joseph Folahan Odunjo si afẹfẹ rere.