Conjoined twins: Ilé ìwòsàn l'Àbuja ti ya àwọn ìbejì tí wọ́n sọpọ̀ láyà

Naijiria
Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ ìbejì tí wọ́n sopọ̀ ní ìsàlẹ̀ ikùn ni wọ́n ti ṣisẹ́ abẹ fún láti tú wọn ká, àmọ́ ìgbà àkọ́kọ́ nì yíì tí àwọn dokìta náà yóò ya ìbejì tí wọ́n sopọ̀ láyà.

Àwọn dokita mejidinlọgọrin lorilẹ-ede Naijiria ti ṣisẹ papọ lati ya awọn ibeji to sopọ ni aya lati ọdun 2018 ti wọn ti bi wọn.

Olori awọn dokita to ṣe iṣẹ abẹ naa, Emmanuel Ameh sọ fun BBC pẹ Oṣu Kọkanla, ọdun to kọja ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ abẹ lati pin Goodness ati Mercy Martins ni aya ati ikun oke.

O ni awọn ọmọ naa ti gbadun, iṣẹ abẹ ti pari, awọn ibeji si ti wa ni alaafia bayii lati lọ si ile.

Ameh ni iṣẹ abẹ naa yẹ ko na awọn obi awọn ibeji naa ni ẹgbẹrun lọna marundinlogoji owo ilẹ okeere dọla $55,000 (£42,000).

Dokita Ameh fikun un wi pe o gba awọn dokita naa ni wakati mejila lati fi ṣe iṣẹ abẹ naa, ti awọn dokita mejidinlọgọrin naa si pin ara wọn si ọna meji lati ṣiṣẹ abẹ naa.

Naijiria

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Anneh

Amọ, ọfẹ ni awọn oṣiṣẹ ile iwosan ijọba ti National Hospital Abuja ṣe isẹ abẹ naa fun wọn nitori awn obi awọn ibeji naa- Michael Edeh ati Maria Onya Martins ko le e san owo ile iwosan naa.

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Owo ti ọkọ to jẹ baba awọn ọmọ naa n pa nibi iṣẹ kunlekunle ni wọn fi n tọju awọn ọmọ naa tẹlẹ lati igba to ti bi wọn.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Osu Kẹjọ, ọdun 2018 ni awọn obi naa gbe awọn ọmọ naa wa si ile iwosan leyin ti wọn bi awọn ọmọ ibeji ọhun.

Naijiria

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Anneh

Ṣugbọn ko ṣeeṣe fun awọn dokita lati ṣe isẹ abẹ fun wọn ni igba naa nitori ara wọn ko le daadaa.

Ile-iwosan ijọba ni awọn ibeji naa ti gba iwosan fun osu meedogun, ti okun wọn si ti le daadaa, ki wọn to le ṣe iṣẹ abẹ naa.

Ọ̀pọ̀ ìbejì tí wọ́n sopọ̀ ní ìsàlẹ̀ ikùn bii mọkanla ni wọ́n ti ṣisẹ́ abẹ fún láti tú wọn ká, àmọ́ ìgbà àkọ́kọ́ nì yíì tí àwọn dokìta náà yóò ya ìbejì tí wọ́n sopọ̀ láyà.

Adari ile iwosan naa, Jaff Momoh ni iṣẹ abẹ awọn ibeji naa yatọ ninu eleyii ti awọn ti n ṣe nitori o nii ṣe pẹ̀lu isale igba aya wọn ati ẹdọfooro.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Baba awọn ibeji naa ni inu oun dun pupọ lati ri wi pe awọn mọ mejeeji wa ni alaafia, ti awọn si n woye lati pada sile lai pẹ.

Iya awọn ibeji naa sọ wi pe inu oun dun de bi wi pe oun ko mọ oun ti oun le sọ, ti o si dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa fun bi wọn ṣe saanu fun wọn.

Àkọlé fídíò, Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀

O ni inu oun bajẹ nigba ti oun bi awọn ibeji naa, amọ ayọ oun ti kun bayii ti oun ti ri wọn ni alaafia.

Minisita fun eto ilẹra lorilẹ-ede Naijiria, Osagie Emmanuel to ṣe abẹwo si ile iwosan naa gboriyin fun iṣẹ ti awọn dokiat naa ṣe.

Bakan naa ni Minisita fun ọrọ to niiṣe pẹ awọn obinrin lorilẹ-ede Naijiria fikun un wi pe oun yoo fun Abilẹkọ Martins ni iṣẹ ki o ba le e ran idile rẹ lọwọ.