Cameroon: Ọmọdé tó ń ṣeré pẹ̀lú àdò olóró ló fa ìbúgbàmu Borno

Oríṣun àwòrán, Muhammadu, Olugbe ilu Gamborou
Ile iṣẹ ọmọ ogun orilẹ-ede Cameroon ti ni kosi otitọ ninu iroyin pe awọn ikọ Boko haram lo sekupa awọn eniyan ni ibode Naijiria ati Cameroon.
Agbẹnusọ ikọ ọmọ ogun Cameroon, Cyrille Serge Atonfack Guemo sọ wi pe awọn ọmọde meji to n fi iyẹpẹ sere lo n fi ado oloro sere lai mọ, ki o to di wi pe o wa bu gbamu mọ wọn loju.
Cameroon ati Naijiria jọ n pin ibode kan naa ni agbeegbe afara El Beid ati Fotocol ni agbeegbe Cameroon.
Awọn ologun naa fikun un wi pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ọhun lati fi idi otitọ mọlẹ.
Wọn tun sọ pe eniyan mẹsan an lo ku ninu iṣẹlẹ naa, nigba ti awọn mọkandinlọgbọn to farapa si n gba itọju lọwọ ni ile iwosan to wa ni Cameroon ati Naijiria.
Ẹni mẹ́sàn án dòkú; mẹ́ta farapa nínú ìkọlù aàlà Borno àti Cameroon
Aala to wa laarin Naijiria ati Cameroon ni ado oloro naa ti deede dun to si jẹ ki ọpọ fi ara pa.

Oríṣun àwòrán, @Yunus Wada
Ori afara El Beid to pin Naijiria ati orilẹ-ede Cameroon nitosi ilu Fotokol.
Wọn ni o kere tan eeyan mẹsan an lo ti ku bayii ti o le ni mọkandinlọgbọn eeyan si farapa yanayana.
Oju wa lara awọn obinrin Cameroon ati Naijiria ni won fura si pe jiju ado oloro naa ko ṣẹyin wọn.
Awọn alase Naijiria ati Cameroon ko tii ṣo nkankan nipa iṣẹlẹ yii bẹẹ ko tii si awọn ikọ tabi ẹgbẹ kankan to tii wa sọ pe awọn ni wọn ṣe ikọlu naa.
Ṣugbọn awọn akọroyin Cameroon ni ko ṣẹyin awọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram ti wọn ti sọrọ lọhun.
Awọn miran to tun farapa ni awọn to bẹ sodo naa lati sa asala fun ẹmi wọn kuro lori afara naa.
Awọn Boko Haram ti ṣẹ ọpọlọpọ ọṣẹ́ ni Naijiria, Nijer, Cameroon, Lake Chad yatọ si ti ipa ti awọn ọmọ ogun to darapọ lawọn orilẹ-ede yii n ko lati fi gbogun ti Boko Haram.
Lọjọ Abamẹta to kọja ni orilẹ-ede Chad kede pe ki awọn ọmọ ogun oun maa pada bọ wa sile kuro ni Naijiria.
















