Kano: À ti fa àwọn oníbalòpọ̀ akọsákọ tí a mú le òbi wọ́n lọ́wọ́- Ọlọpàá Hisbah

Oríṣun àwòrán, Other
Àwọn ọlọpàá Hisbah ni ìpínlẹ Kano ni àwọn ti mú àwọn kò sakọ kò sabo àti àwọn ọkunrin to maa n wọ àṣọ bi obinrin mẹẹdogun ni agbegbe Sabuwar Gandu ni ìpínlẹ̀ Kano.
Igbakeji ọgá Hisbah ni ipinlẹ Kano Shehu Tasi'u ní kété ti wọ́n ta awọn lólobó pé ayẹyẹ kan yóò wáye ti àwọn oníbalopọ̀ akọsákọ tabi Amúra bii obinrin ni Sabujwar Gandu ni wọ́n ti gba ibẹ̀ lọ ti wọ́n si mú àwọn to péjú si ibi ayẹyẹ náà nítori pe ìjọba n gbìyànjú láti kò irú iwà bẹ́ẹ̀ kúrò nilẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọpáà Hisbah ṣàlàyé pé àwọn bá àwọn ènìyàn wọ́nyi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgbàníyànju lẹ́yin náà ni wọ́n ko wọ́n lọ si ilé àwọn òbi wọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ fún akọroyìn BBC pé kété ti wọ́n dé ilé àwọn òbi wọ́n, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn òbi wọ́n nitori pé wọ́n kò mọ pé ǹkan ti àwọn ọmọ wọ́n n dánwò niyẹn.
Ìgbákeji ọ̀gá àgbà náà wá sàlàyé pé àwọn ti fa wọ́n le àwọn òbí wọn lọ́wọ́, ti awọn sì fi lée pé wọ́n gbọdọ̀ máa pèsè wọ́n nígbàkúùgbà ti àwọn bá nílo láti ri wọ́n.
Tẹ ò bá gbàgbé, wọ́n mu àwọn ènìyàn náà ni ọjọbọ níbi ayẹyẹ ti àwọn akẹkọọjáde Fasiti Bayero ní Kano pé láti ṣe ayẹyẹ àṣeyọri ètò ẹkọ́ wọ́n.












