Iran war: Ẹgbẹ́ Shiites wọ́de l'Abuja, wọ́n jó Àsìá Amẹ́ríkà

Àwọ́n ọmọ ẹgbẹ́ Islamic Movement of Naigeria (IMN) ti gbogbo ènìyàn mọ si Shi'ites lọ́jọ́ Ajé ti ya si ìgboro lágbègbè ilé ìtajà Bannex ni Wuse nílú Abuja.
Won n ṣe iwọde nítori Olóri ọmọ ogun Iran Quasm Soleimani ti àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹrika pa lọ́jọ́ Ẹtì to kọja.
Bákan náà ni wọ́n pè fún ìtúsilẹ̀ adari wọ́n Sheikh Ibraheem El-Zakzeky àti ìyàwó rẹ̀ Zeenat ti wọ́n wà ni àhámọ lọ́wọ́lọ́wọ́.
Awọ́n olùfẹhonuhan náà bọ́ si ìgbòro Abuja ti wọ́n sì n pariwo àwọn òrin ọ̀tẹ bí " Iku ni fún Amerika"
Bakan náà ni wọ́n dána sun àsìá orílẹ́-èdè Amerika tí wọ́n sì gbé àwọn àkọle to bẹnu àtẹ lu pípa ti Amerika pa olóri ọmọ ogun Iran sọ́wọ́.

- C. Ronaldo fi góòlù mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ ọdún 2020
- Kano: À ti fa àwọn oníbalòpọ̀ akọsákọ tí a mú le òbi wọ́n lọ́wọ́- Ọlọpàá Hisbah
- Wo àwọn ọ̀tá tó ń da orílẹ̀èdè Nàìjíríà láàmú
- 'Kò bá má dùn mí tó báyìí bí mi ò bá k'àwé', pé mò ń nu bàtà f'óúnjẹ òòjọ́'
- Irú kí lèyì! Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì í bọ ara rẹ̀ náà níkùn









