Amojúẹ̀rọ tó ń nu bàtà fi wá oúnjẹ òòjọ́

Ọgbẹni Chekole n nu Bata

Chekole Menberu to ti di ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn bayii ni ọpọlọpọ ireti giga nigba ti kawe ja pẹlu oye fasiti onipele kinni ninu imọ chemical Engineering lọdun meji sẹyin ni orilẹede Ethiopia.

O jẹ asiko idunnu fun un pẹlu bi o ba boju wo iye ọdun to ti fi ṣe laalaa ati gbogbo iṣoro to ti la kọja lati de ipo yii.

Fun ọpọlọpọ ọdun lo ti fi nu bata fun awọn eeyan lẹgbẹ ọna lati fi tọju ara rẹ, lati kekere ni Ọgbẹni Chekole ti fi wa iṣẹ kiri loju titi.

Lati igba to ti jẹ ọmọde ni baba rẹ ti ku to si ti n gbe pẹlu awọn obi baba rẹ ni agbegbe Fogera ni ẹkun Amhara. Iya rẹ si ti fẹ ọkọ mii.

Gbogbo igba ni mo maa n kun lọ si ileewe

O wu Chekole gan ko kawe ṣugbọn awọn baba baba rẹ ko lowo ati tọ ọ.

Lo ba kọri si ile ẹgbọn baba rẹ lati maa ṣe aṣọ́ ẹran ọ̀sìn. Ṣugbọn o si tun n ni ireti pe awọn obi baba oun yoo le ran oun lọwọ.

"Gbogbo igba ni mo maa n fi ikanra sọ pe awọn obi baba mi ko le ran mi nilewe", o sọ fun BBC.

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'
Ọgbẹni Chekole

Nigba to ya, baba baba rẹ gbọ si ẹbẹ rẹ o si mu u lọ forukọ silẹ ni ileewe alakọbẹrẹ kan ni ilu to n jẹ Woreta.

Ṣugbọn iranwọ baba baba rẹ wa sopin nigba to de ipele keji.

"Mo ni lati jade sita lati wa ọna ati ran ara mi lọwọ"

Pẹlu iranlọwọ ọrẹ rẹ kan to maa n kun bata, Whekole bẹrẹ si ni nu bata fawọn eeyan.

Chekole ni "Mo ro wi pe ninu baba lee ran mi lọwọ. Odidi idaji ọjọ kanni mo fi n ṣiṣẹ lojọ ti maa si fi idaji to ku ka iwe".

Aye le mọ mi. Ṣugbọn itan awọn eeyan to n ronu bii temi ṣugbọn ti wọn di dokita ati imọ ẹrọ gba mi niyanju.

'Ohun gbogbo ka mi lara gan'

Gbogbo saa ẹkọ rẹ nileewe lo fun un ni wahala tori o ni lati ra aṣọ ileewe eyi ti ko si lowo rẹ.

"Ẹkọ na mi lowo gaan", eyi lo sọ.

"Ọpọlọpọ igba ipọnju ni mo la kọja ṣugbọn mi o ni gbagbe bi o ṣe ka mi lara gan nigba ti mo fi de ipele ẹkọ kẹjọ ati ikẹwa atii lọdun ti mo wọ ile iwe fasiti."

Ayẹyẹ ikẹkọgboye Fasiti Bahir

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pẹlu gbogbo nkan to foju ri, o ṣaa tiraka wọ ile iwe fasiti Bahir Dar ni olu ilu Amhara nibi to ti kawe gboye imọ Chemical Engineering.

"Idi ti mo fi lọ fun imọ ẹkọ yii ni wi pe awuyewuye wa pe orilẹede wa nilo ọpọlọpọ amojuẹrọ. Mo si nireti pe mo maa ri iṣẹ ni kete ti mo ba kawe ja".

O ri iranwọ diẹ nigba ti lẹta kan wa si ileewe rẹ lati ilu ibi rẹ pe ko ni oluranlọwọ kankan. Fasiti rẹ ba bẹrẹ si ni san 200 birr ($10) loṣu.

"Mo tun maa n ri iranwọ latd awọn alabagbe mi atawọn ọrẹ mi ṣugbọn nigba ti ọjọ ikọkgboye mi n sunmọ etile, ẹru bẹrẹ si ni ba mi boya mo maa ri iṣẹ".

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

'Mi o lori iṣẹ'

Lọdun 2017 ni Ọgbẹni Chekole kẹkọọ gboye to si fẹ gun le wiwa iṣẹ loju ẹsẹ.

Ṣugbọn ori ko gbe e.

"Oṣu mẹta ni mo fi n wa iṣẹ ni Addis Ababa. Mo rin kaakiri ilu fun iṣẹ ṣugbn mi o lori rẹ.

Koda o rinrinajo kaakiri ati kọja ilu rẹ, "mo tun wa iṣẹ lai lo iwe ẹri fasiti rẹ ṣugbọn ọpọlọpọ igba ni wọn n kọ iwe iwaṣẹ mi.

'Mo pada si fasiti'

Lẹyin ọpọlọpọ oṣu wiwa iṣẹ ti iwẹ ẹri rẹ ko si so eso rere, o pada si ilu Bahir Dar - lati bẹrẹ iṣẹ ti ko lero pe o le pada si.

"Nigba ti ko sohun ti mo le ṣe mọ, mo pada si ẹsẹ aarọ ki n maa nu bata".

Taa ba wa beere boya o kabamọ pe o tilẹ ka iwe, o ni inu ko ba ma bi oun to bayii bi ko ba ka iwe.

"Ẹkọ yii na mi lowo gan, mi o si jere kankan nibẹ, mi o ba ma ti ṣe laalaa to bẹẹ lori rẹ.

Ọgbẹni Chekole

Bi awọn oluko mi to mọ mi ni fasiti ba ri mi, ara wọn a ka ti wọn a si ka oju kuro. Ṣugbọn awọn mii a gba mi niyanju wọn a si fun mi lowo."

Awọn ọrẹ mi nileewe gan maa n mọọmọ wa nu bata bi bata wọn gan ko tilẹ dọti tori ki wn le fun mi lowo.

Ẹwẹ, o ni ireti, ninu ohun gbogbo pe yoo ri iṣẹ to dara. Mo ṣi maa n lọ wo awọn patako ti wọn ti n polowo iṣẹ," Chekole sọ.