Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì í bọ ara rẹ̀ náà níkùn

Ijọ Kenya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pásítọ̀ gún ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá tì í bọ ara rẹ̀ náà níkùn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Pasitọ ijọ kan ni Kenya ti gun iyawo rẹ lọbẹ pa lọjọ Aiku lori aga iwaasu ninu ṣọọṣi ti awọn mejeji jọ da silẹni ilu kan ni Mombasa, ni orilẹ-ede Kenya.

Awọn olujosin to wa nile ijọsin lọjọ naa sọ fun awọn akọroyin pe Pasitọ naa, Elisha Misiko jokoo niwaju ninu ijọ

Nibi to joko si nibẹ si lo ti dide lọ ba iyawo rẹ lori pẹpẹ to si gun un pẹlu ọbẹ to fi pamọ sabẹ ẹwu to wọ.

Lẹyin eyi lo lo ọbẹ kan naa lati fi gun ikun ara rẹ, bi awọn ọmọ ijọ ṣe tun fẹ sare si wọn lori pẹpẹ lo fi ọbẹ naa ge ara rẹ rẹ ní ọ̀fun.

Loju ẹsẹ ni Elisha gbẹmi mi nigba ti iyawo rẹ ku nile iwosan.

Àkọlé fídíò, Oyo Fire: Dukia ṣófo, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá faragbọta níbí iná tó jó ọjà Akesan

Ṣaaju ki ọrọ yii to ṣẹlẹ, tọkọ taya yii ti ni aawọ lori tani yoo maa ṣakoso ijọ gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Nation ṣe sọ ọ.

Àkọlé fídíò, 'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

Gbogbo bo ṣe ṣẹlẹ yii lawọn ti o ṣoju wọn koro ko iroyin ro fun awọn akọroyin nipa ohun to ti n ṣẹlẹ ninu ile pasitọ yii ati iyawo rẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Arabinrin kan ni ṣe ni ọkọ n fi iya jẹ iyawo rẹ to bi ọmọ mẹrin fun un to n ṣe e baṣu baṣu titi ti wọn fi pinya.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'