Àsọtẹ́lẹ̀: Pásítọ̀ ríran pé Ìmáàmù yóò kú

Oríṣun àwòrán, Glorious world power ministry/Facebook
Àwọn ọ̀dọ́ mùsùlùmí tí ya wọ ilé ìjọsìn kan ní orílẹ̀-èdè Ghana, lẹ́yìn ti pásítọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Imaamu àgbà orilẹ̀-èdè Ghana yóò kú lọ́dún 2019.
Ohun èlò orin, fèrèsé, àti àga inú ṣọ́sọ̀sì ní wọn bàjẹ́ nígbà ti àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún ya wọ ilé ìjọsìn ẹni ọ̀wọ̀, Isaac Owusu-bempah ní ìlú Accra.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Imaam Nuhu Sharabutu lòdì sí ìgbésẹ̀ tí àwọn ọdọ́ náà gbé.
Sisọ asọtẹ́lẹ̀ lopin ọdun laarin awọn ìjọ ọmọlẹyin Kristi kan jẹ́ ǹkan tó wọ́pọ̀, tí àwọn ènìyàn kan sì máà ń fẹ ní ilẹ̀ Afíríka, èyí máa ń sábà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ǹkan gbòógì tí yóò ṣẹlẹ̀, tó fi mọ́ ikú àwọn èèkan nínú ìlú.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Irú rẹ̀ ní èyí tó wáyé ní ọdún 2016, nígbà ti ìlú mọ̀ọ́ká pásítọ̀ T.B Joshua sọ tẹ́lẹ̀ pé, Hillary Clinton yoo bori Donald Trump lati di ààrẹ orilẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Àwọn alátako rẹ̀ fí ṣe yẹ̀yẹ́ lẹ́yìn ti Trump jáwé olúbori. Ẹyìn náà lo pa asọtẹ́lẹ̀ náà rẹ́.
Lásìkò tó ń wàásù ní òpín ọdún, Owusu-Bempah sọ àsọ́tẹ́lẹ̀ tí ọdún 2019, tó fí mọ ikú Imaam Sharabutu.
Àwọn ọ̀dọ́ mùsùlùmí to tako iran náà sọ fún olùsọ́-àgùtàn ọ̀hún pé, kó tọrọ àforíjì, sùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Idi ree ti wọn se fa ibinu yọ, ti wọn si ba awọn ohun eelo kan jẹ ninu ile ijọsin naa.
Imaam Sharabutu tí wa pè fún ìdákẹ́rọ́rọ́, o ní kí wọn dáríji pàsítọ̀ náà tó jẹ́ ọ̀kan gbòógi nínú àwọn pasítọ̀ ní orílẹ̀-èdè Ghana.
Ghana jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kìrìstẹ́nì pọ sí, kò sì tíì si nínu 'ìtàn orilẹ̀-èdè náà pé ìjà ẹ̀sin bẹ́ sílẹ̀ ri.













