Yomi Fabiyi: Èmi ti dáríjì ẹ́, kí ìwọ náà jọ̀wọ́ dáríjì mí

Toyin Abraham, Yomi Fabiyi ati Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àkọlé àwòrán, Ìjà yíí bẹ̀rẹ̀ ní ǹkan bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn lẹ́yìn tí Yomi Fabiyi pe Toyin Abraham ní alágàbàgebè nítorí ìjà pẹ̀lú Mercy Aigbe.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja osere, Yomi Fabiyi ti kesi akẹgbẹ rẹ, Toyin Abraham wi pe ki wọn pari ija to wa laarin awọn mejeeji.

Yomi Fabiyi tọrọ idariji lọwọ Toyin Abraham lori ẹrọ ikansiraẹni Instagram rẹ, ki Toyin si fọwọ wọnu ninu ọdun tuntun.

Fabiyi fi kun un wi pe gbogbo ẹṣẹ ti Toyin ṣẹ oun ni oun ti dariji, ki Toyin naa ṣe bakan naa, ki ohun gbogbo si pada si ipo laarin wọn.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ti a ko ba gbagbe, ija laarin Toyin Abraham ati Yomi Fabiyi bẹrẹ ni nkan bii ọdun diẹ sẹyin, lẹyin ti Yomi Fabiyi pe Toyin Abraham ni alagabagebe nitori ija to wa laaarin Toyin Abraham ati oṣerebinrin miiran, Mercy Aigbe.