Boko Haram: Bàlúù ogun Nàìjíríà kan ti já lójú ìjà pẹ̀lú Boko Haram

Oríṣun àwòrán, NAF
Ilé iṣẹ́ ogun oju ofurufu Naijiria ti sọ pe ọmọ ogun marun-un lo ti ku ninu baluu awọn ọmọ ogun ofurufu to ja nirọlẹ ọjọru lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.
Eyi ṣẹlẹ nigba ti awọn ọmọ ogun n koju ẹgbẹ Boko Haram ni agbegbe Damasak lẹba ibode Naijiria pẹlu orilẹede Niger.
Ọrọ kan ti agbẹnusọ ile iṣẹ ogun ofurufu fi sita jẹ ko di mimọ pe wọn ti ri oku wọn. Ẹwẹ, ko ṣi tii si aridaju ohun to fa ijamba inu afẹfẹ naa.
Baalu ogun naa, eleyi ti wọn ni o wa lara awọn baalu ogun ti wọn n lo fi kọju ija sawọn agbebọn Boko Haram, ja lasiko ti ina ogun nlọ lakọlakọ laarin awọn ọmọ ogun Naijiria atawọn agbebọn Boko Haram.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu atẹjade kan eyi ti ileeṣẹ ọmọogun ofurufu orilẹede Naijiria fi sita, baluu naa n ṣe atilẹyin fawọn ọmọogun oriilẹ ti wọn n doju kọ awọn ikọ Boko Haram kan lagbegbe Damasak nitosi aala orilẹede Naijiria pẹlu Niger.
Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu ṣi n beere ibeere lori ohun to ṣokunfa jija ti baluu ogun na ja.
Itaporogan laarin awọn ọmọogun atawọn ikọ Boko haram lẹnu lọwọlọwọ yii n gbona janjan eleyii to si ti ṣokunfa iku ọpọ awọn ọmọogun, ti awọn eeyan naa si tun ti ko nnkan ogun wọn lọ.









