Minimum wage: NLC ní Gómìnà tí kò bá san ẹ̀kúnwó oṣù ń tàpá sí òfin Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ oṣiṣẹ ti ni ko si idi fun awọn gomina to ba ni awọn ko lee san ẹkunwo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ lati ṣi maa wa nipo.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣalaye pe, gomina yowu to ba ni oun ko lee san ẹkunwo oṣu tuntun naa, n tapa si iwe ofin orilẹede Naijiria, eyi ti wọn bura lati maa tẹlẹ ni tiku-tiye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Akọwe agba fun ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC lorilẹede Naijiria, Peter Ozo-Eson ṣalaye pe, ilakalẹ ofin ni sisan owo oṣu tuntun fun oṣiṣẹ, atipe gomina ipinlẹ to ba nipa lati san ju bẹẹ lọ lee san an.
"Ẹgbẹ oṣiṣẹ ko ṣetan lati gbẹyin bẹbọjẹ lori eto idibo apapọ to n bọ lọna. A ti bẹrẹ ọrọ lori ẹkunwo oṣu tuntun yii fun ọdun meji, nitorinaa, eeyan kan ko lee wa maa halẹ mọ wa pe a fẹ da ilana idibo ru."
Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ni bi ohunkohun ba ṣe eto idibo apapọ ọdun 2019, ijọba apapọ ni ki awọn araalu o dimu.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fi kun pe, ẹ̀ṣẹ̀ tó la ìyọnípò kúrò lọ fáwọn gómìnà ni bí wọ́n bá kùnà láti san ẹ̀kúnwó oṣù tuntun fún òṣìṣẹ́.









