ASUU ní ìjọba àpapọ̀ ni kò fẹ́ kí ìyanṣẹ́lódì àwọn o pari

Ẹnu iloro fasiti Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn olùkọ́ fásitì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì nítorí àwọn àdéhun tí ìjọba àpapọ̀ kùnà láti mú ṣẹ

Iyanṣẹlodi ẹgbẹ olukọ fasiti lorilẹ-ede Naijiria ti wọ oṣu meji bayii.

Ọpọ awọn akẹkọ to yẹ ko ti kẹkọ gboye bayii ni irinajo wọn ti n fi ẹsẹ kan tiro bayii ti ọpọ akẹkọ atawọn obi si n ti pẹpẹ adura kan bọ si omiran nitori atiwọle pada awọn akẹkọ yii.

Nitori naa nigbati iroyin jade pe ijọba apapọ ti gbe N15.89 biliọnu silẹ gẹgẹ ara ohun ti awọn olukọ fasiti naa n ja fun, idunnu nla lo gba ọkan ọpọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa ko daju pe idunnu to fi ẹsẹ rinlẹ ni eyi yoo jẹ nitori ASUU ti sọ laifọtape pe yatọ si pe awọn ko tii mọ si owo ti wọn ni ijọba apapọ gbe silẹ naa, owo naa, to ba jẹ lootọ jinna si ohun ti o so adehun to wa laaarin awọn ati ijọba apapọ rọ.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ aarẹ apapọ ẹgbẹ olukọ fasiti, ASUU lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Biọdun Ogunyẹmi ṣalaye pe aijolootọ ijọba apapọ lori ijiroro to n waye lori imuṣẹ adehun eyi to fa iyanṣẹlodi naa.

Awọn akẹkọ fasiti kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ní oṣù kọkànlá ọdun 2018 ni àwọn olùkọ́ fásitì lórílẹ̀èdè Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Ọjọgbọn Ogunyẹmi ni ipele mẹta ni ohun ti awọn n ja fun wa. Owo ajẹẹlẹ owo oṣu fun awọn olukọ fasiti kan, owo fun atunṣe awọn fasiti, ati owo ajẹmọnu ti wọn pe earned Allowance. O ni ninu gbogbo ohun wọnyii eleyi ti wọn ni ijọba apapọ gbe kalẹ yii lo kere ju ati pe kii tilẹ n ṣe gbogbo fasiti lo kan.

"Awa kọ lo n pagidina bi iyanju yoo ṣe de ba iyanṣẹlodi yii bi ko ṣe ijọba. A rii pe, n ṣe ni ijọba kan n ṣe lilọ bibọ loju kan naa lori awọn ijiroro wa gbogbo. Owo ti wọn ni ijọba gbe jade yii ko ja mọ ohunkohun ninu ohun gan an ti a n beere. Ijọba pẹlu si mọ eyii."

Àkọlé fídíò, Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú

Nigba ti yoo dahun ibeere lori boya opin iyanṣẹlodi wọn wa nitosi, aarẹ apapọ ẹgbẹ olukọ fasiti lorilẹede Naijiria, ASUU ni ni bi ọrọ ṣe n lọ yii ko daju o nitori ijọba ko tii sunmọ ibeere adehun wọn.

"Ko si igba kan ti a binu jade kuro nibi ipade wa pẹlu ijọba ṣugbọn ijọba apapọ ko jẹ olootọ si ijiroro pẹlu ASUU lori adehun yii. Ni temi o, ijọba apapọ gan an lo n fa iyanṣlodi yii siwaju."