Ekiti: Ìyàwó gómìnà Èkìtì rọ àwọn obìnrin lóríi gbígbẹ̀bí sílé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oniruuru iburdo ìrọbí ni awọn obinrin n gba bimọ sí.
Paapaa ni ilẹ Afirika atawọn orilẹ-ede to ku diẹ kaa to fun lagbaye, awọn ọna miran yatọ si ileewosan ni awọn eeyan n lo fun igbẹbi nitori ọpọlọpọ ipenija ninu eyi ti ọda owo wa.
Iwadii ajọ UNICEF, WHO, UNFPA ati banki agbaye kan fi idi rẹ mulẹ pe ninu ẹgbẹrun lọna ọgọrun igbẹbi, o din diẹ ni ẹgbẹta ninu wọn ni kii ruu la.
Bakan naa si ni iwadi kan ti banki agbaye gbe sita lọdun 2011 fihan pe ida mọkandinlaadọta ninu ọgọrun un awọn to n bimọ lorilẹ-ede Naijiria lo jẹ wi pe kii ṣe ileewosan ni wọn bimọ si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nibayii, iyawo gomina ipinlẹ Ekiti, Bisi Fayẹmi ti rọ awọn obinrin nipinlẹ Ekiti lati yago fun bibimọ sile tabi si ọdọ awọn agbẹbi agboole ati ibilẹ.
O ni ewu to wa ninu awọn igbẹbi bẹẹ kun ara wahala iṣoro igbẹbi ti awọn iwadii wọnyii gbe kalẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni ko si idi fun obinrin kankan ni ipinlẹ Ekiti lati bi ọmọ sile tabi awọn ile agbẹbi ibilẹ.
Amọṣa bi a ba woo finifini, iṣẹ oun oṣi, aṣa ati iṣẹṣe tofi mọ aisi eto ilera alabọde kun ara ohun ti o n sun awọn aboyun lọ si ile igbẹbi ibilẹ.
O ni ipa gbogbo ni ijọba yoo sa lati rii pe eto ilera to mu irọrun dani wa larọwọto mutumuwa, paapaa julọ awọn obinrin ati ọmọ wẹwẹ.












