ASUU Strike: Irọ̀ ni pé ìjọba fún wa ní owó tó tó N15.89bn

Ami idanimọ ẹgbẹ́ ASUU

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ẹgbẹ awọn Olukọ Fasiti, ASSU ti ni awọn ko mọ nkankan nipa owo to le ni biliọnu mẹẹdogun ti iroyin ni wọn fun ile ẹkọ giga fasiti.

ASSU sọ eyi lẹyin ti wọn gunle iyansẹlodi lati osu meji sẹhin lori ẹsun pe ijọba ko san awọn owo ajẹmọnu wọn ati awọn owo osu ti wọn jẹ awọn olukọ.

Aarẹ ẹgbẹ ASSU, Ọjogbon Biodun Ogunyemi lo fi eleyii lede ni ipinlẹ Eko lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ.

Ogunyẹmi fikun un wi pe lootọ ni minisita fun ọrọ osisẹ pe oun lori aago pe awọn ti gbe igbesẹ lori iyansẹlodi wọn, amọ o ni oun ko mọ iru igbesẹ ti ijọba gbe.

Aarẹ ẹgbẹ ASSU ni minisita naa ni ijiroro ati ipade yoo waye ni Ọjọ Aje, ọsẹ to n bọ.

Àkọlé fídíò, Wòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé