2019 Elections: Ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùba ń ṣẹlẹ̀ ní gbọ̀ngàn fásitì ìlú Ilorin

Nibayii ti eto idibo gbogbo gboo n kanlẹkun gbọn-gbọn ni orilẹ-ede Naijiria, oniruuru aayan ni ileesẹ BBC Yoruba ti n ṣe lati rii daju pe awọn araalu ni anfaani lati yan aarẹ, awọn gomina ati awọn aṣofin to pegede, fi gbọọrọ jẹka.
Yatọ si pe a n kede awọn iroyin nipa eto idibo to n bọ naa loore-koore, BBC Yoruba ti ṣeto lati ṣe ariyanjiyan fawọn eeyan to n dije lati du ipo gomina ninu eto idibo naa, paapa awọn to wa lẹkun ilẹ Oodua.
Ipinlẹ Kwara làkọ́kọ́, lónìí sì ni yóò wáyé gẹ́gẹ́ bí BBC Yoruba ti ṣide ipade itagbangba naa, nibi ti eto ariyanjiyan yoo ti waye laarin awọn oludije latinu ẹgbẹ oselu marun un tawọn eeyan nifẹ si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Inu ọgba fasiti Ilọrin ni eto naa yoo ti waye ni Ọjọbọ, ọjọ kẹwaa, osu Kinni, ọdun 2019.

Oríṣun àwòrán, Razak Atunwa
Saaju ka to mu awọn oludije latinu ẹgbẹ oṣelu maraarun naa, ni BBC Yoruba ti kọkọ beere ero awọn araalu ni ipinlẹ kọọkan, nipa awọn ẹgbẹ oṣelu marun ti wọn gbaju-gbaja julọ ninu gbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa lorilẹede yii, ti wọn n fẹ ki awọn oludije wọn kopa ninu ariyanjiyan naa.

Oríṣun àwòrán, @Ayorinde Adedoyin
Awọn ẹgbẹ oselu marun un to lewaju ni ẹgbẹ oselu PDP, APC, Accord, Labour ati ANRP.
Nitori naa, awọn asoju ẹgbẹ oselu maraarun, ni ireti wa pe yoo kopa ninu eto ipade ita gbangba naa, iyẹn Ọmọọba Ayọrinde Adedoyin ti ẹgbẹ oṣelu Accord, Alhaji Abdulrazak Abdulrahman, ti ẹgbẹ oṣelu APC ati Komuredi issa Arẹmu, ti ẹgbẹ oṣelu Labour.

Oríṣun àwòrán, @Abdulrazak Abdulrahman
Awọn iyoku ni Asofin Abdulrasak Atunwa, ti ẹgbẹ oṣelu PDP, ati Ọmọwe Abdulmunin Yinka Ajia, ti ẹgbé oṣelu ANRP.

Oríṣun àwòrán, @Issa Aremu
BBC Yoruba wa n kesi awọn eeyan ipinlẹ Kwara to ba nifẹ lati peju sibi ipade ita gbangba naa pe, ki wọn lọ fi orukọ wọn silẹ lori ikanni isalẹ yii.
https://bit.ly/2rHOXzO

Oríṣun àwòrán, Yinka Ajia
Ẹ ku oju lọna ipade yii o pẹlu BBC Yoruba!













