Lagos APC Rally: MC Oluọmọ fara gb'ọ̀bẹ níbi ìpolongo ìbò

Nibi ipolongo ibo APC to waye nipinlẹ Eko, wahala bẹ silẹ, Musiliu Akinsanya ti gbogbo eniyan mọ si MC Oluọmọ si fara gbọgbẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti kede pe wọn n wa ọkunrin kan, Mustapha Adekunle, ti inagijẹ rẹ n jẹ seigo.
Iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ ni pe wọn fi ẹsun kan Seigo ni pe o gbiyanju lati da eto ipolongo ibo ita gbangba ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ṣe nipinlẹ naa.
Bakan naa la gbọ wi pe nibi wahala to waye lasiko ipolongo ọhun ti oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ APC, Babajide Sanwo-Olu fi ṣide ipolongo ibo rẹ, ni ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ awakọ eero nipinlẹ Eko, MC Oluọmọ naa fi ara pa.
Iroyin naa sọ pe gígún ni awọn janduku gún Oluọmọ to jẹ oloye ẹgbẹ awọn awakọ lasiko ti wahala naa waye.
Lara awọn ti ọta ibọn ba ni oniroyin kan lati ileeṣẹ iwe iroyin the Nation, Emmanuel Oladesu, Temitọpẹ Ogunbanke lati iwe iroyin NewsTelegraph pẹlu ayaworan ileeṣẹ mohunmaworan Ibilẹ Television, Abiọdun Yusuf atawọn eeyan miran.
Lori eyi, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa l'Eko, Chike Oti ninu ikede kan to fi sita sọ pe lọgan ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn gbe Oluọmọ ati awọn mii to tun farapa lọ si ileewosan fun itọju.
Ati wi pe ki awọn ara ilu fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti ti wọn ba gbọ ohunkohun tabi mọ ibi ti arakunrin Mustapha Adekunle ti wọn fi ẹsun kan wa.












