#ENDSARS: Àṣìta ìbọn ọlọ́pàá ló sọ mọ̀lẹ́bí mi, Adenike di báyìí, wọn ò bí i bẹ́ẹ̀, EndSARS ni dandan o- Toyin Abraham

Toyin abraham ati Adenike adekanle

Oríṣun àwòrán, Instagram/toyin abrahams

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ eeyan lo ti n sọ ọpọ iriri wọn pẹlu awọn agbofinro SARS atawọn ọlọpaa Naijiria.

Ọkan to ba ni lọkan jẹ gidi gan an ni iriri ti gbajugbaja oṣere, Toyin Abraham fi sita nipa ọrẹ bii mọlẹbi rẹ kan, Adenike Adekanle ti aṣita ọta ibọn ọlọpaa sọ ọ di alaabọ ara lọdun 1996.

O ni: "Bayii kọ ni wọn ṣe bi i, ọta ibọn awọn ọlọpaa lo sọ ọ di bayii latọdun 1996 ni Ibadan".

Gẹlẹ bi Toyin ṣe kọ ọrọ tan si abẹ fọto Adenike to fi soju opo instagram rẹ pe ki oun to le sọ ọrọ yii sita, oun ni lati gba aṣẹ lọwọ ọlọrọ ni Adenikẹ to jẹ ọlọrọ gan an ni.

Royin ni: "mi o fi bo mọ. Lootọ sisọ ọrọ yii sita maa n mu iranti aburu wa fun mi ṣugbọn bi yoo ba ti ṣeranwọ fun igbesẹ fifopin si iwa awọn agbofiro SARS yii, ẹ jẹ ka tẹsiwaju".

Toyin Abraham ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje ti aṣita ọta ibọn ọlọpaa ti wọn n pe ni "Stray bullet" ba Adenike ni agbegbe Apata niluu Ibadan, wọn gbe lọ ileewosan.

Àkọlé fídíò, End SARS, End SWAT: Ó pé mi bí SARS kò ṣe sọ mí dolówọ́- Fulani Kwajafa

Toyin ni awọn o tilẹ ko firi awọn ọlọpaa pe ki wọn wa bẹ ẹ wo de bi ti wọn yoo san owo itọju rẹ, ọdun kan gbako si lo fi wa nileewosan.

Gẹgẹ bi o ṣe kọ ọ, nkan bii ago mẹta ọsan ni Adenikẹ kagbako ọta ibọn ọlọpaa lọjọ naa lọdun 1996.

Tori eyi, o gbagbọ pe afi dandan ki wọn fopin si ohun gbogbo to jọ mọ iwa aidaa awọn ọlọpaa ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Sotitobire: Ọkọ mi kò mọ̀ Jegede PDP rí, kódà kò fa ẹnikẹ́ni kalẹ̀ dípò Akeredolu- Bisola

Kanye West, Ozil, Boyega, àti àwọn gbajúmọ̀ ilẹ̀ okèèrè tó ṣàtìlẹyìn fún ìpolongo #ENDSARS

Lati bi ọjọ mẹjọ ti iwọde ati ipolongo ti n lọ ni Naijiria, ọgọọrọ awọn ilumọọka ati gbajumọ kaakiri agbaye lo ti n fi ọrọ kan tabi ikeji ṣe atilẹyin fun ipolongo #ENDSARS.

Boyega, Ozil, Kanye, ati Jidenna

Oríṣun àwòrán, Twitter/instagram

Lara wọn lati ri awọn olorin, agbabọọlu, oṣere ati awọn mii.

O sẹ pataki lati mọ pe ipolongo #ENDSARS ni akori ọrọ to leke kaakiri agbaye lori aye;ujara Twitter ni ọjọ akọkọ to bẹrẹ, to si jẹ ọkan lara akori mẹwa to leke julọ ni Twitter lati igba na.

Lara awọn gbajumọ to ti sọrọ lori iwọde naa ni:

Kanye West

Kanye West

Oríṣun àwòrán, PA

Onkọrin ọmọ ilẹ America, to tun n dije fun ipo aarẹ ilẹ America, Kanye West.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ninu ọrọ to kọ si oju opo Twitter rẹ, o ni oun wa pẹlu awọn arakunrin ati arabinrin oun ni Naijiria, lati fi opin si ifiyajẹni lati ọwọ ọlọpaa, ati pe "ijọba gbọdọ dahun ibeere awọn eniyan".

Big Sean

Ninu ọrọ tiẹ, Big Sean, to n na a jẹ afi orin sọrọ 'Rapper', nilẹ America, o ni oun fi ifẹ oun ranṣẹ si Naijiria, to jẹ orisun oun.

Trey Songz

Oríṣun àwòrán, Trey Songz/twitter

Trey Songz

Ogbontagi akọrin takasufe nilẹ Amẹrica, sọ pe lẹyin ọpọlọpọ iwadii ti oun ṣe, o ye oun daju pe oun to tọ ni igbe awọn eeyan Naijiria lasiko yii.

Koda, aimọye igba lati asiko ti iwọde yii ti bẹrẹ lo ti kọ ọrọ sori Twitter rẹ lati ṣe atilẹyin, ati lati bu ẹnu atẹ lu ipaniyan to n waye lasiko iwọde to n lọ.

Rhapsody

O ṣapejuwe iwọde naa gẹgẹ bi "ija a gbogbo agbaye.

John Boyega

Oríṣun àwòrán, john boyega/instagram

John Boyega

John Boyega, osẹre to jẹ ọmọ Naijiria ati Britain sọ pe "awọn ọdọ ni Naijiria lẹtọ si iṣakoso rere, ati itọni.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ohun to n ṣẹlẹ yii niiṣe pẹlu awọn iṣẹlẹ mii. Mo bẹ yin, ẹ da si ọrọ to wa nilẹ yii."

Jidenna

Oríṣun àwòrán, Jidenna/instagram

Jidenna

Ọmọ Naijiria ati ilẹ America ni Jidenna Theodore Mobisson, to tun jẹ akọrin takasufe naa dasi ọrọ ipolongo ENDSARS.

O sọ pe igbesẹ akọkọ ni titu ileeṣẹ ọlọpaa SARS ka.

Àkọlé fídíò, Àwọn jàndùkú ṣe yabò àwọn olùwọ́de #ENDSARS ní Alausa l'Eko

O ni iru ẹ ti waye ri. "A ni lati kọ awujọ ti yoo mu ki awọn ọmọ Naijiria ni ifọkanbalẹ pe ko si ewu fun wọn.

Ẹ jẹ ki eyi jẹ ara ijijagbara tako iwa ibajẹ, ati ipe si ijọba lati sin wa lotitọ.

Diddy

Agba ọjẹ olorin, ati oludasilẹ ileeṣẹ kan to n gbe orin jade nilẹ America, Sean John Combs, ti ọpọ mọ si Diddy, naa da si ọrọ ipolongo #ENDSARS.

Ninu ọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ, o ni ọmọ Naijiria to jẹ akọrin, Burna Boy, lo pe oun lati fi nkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria to o l'eti.

"Nkan ti mo gbọ ba mi lọkan jẹ, ma a ṣe iranlọwọ ni ọna ti mo ba l'agbara.

O fi kun pe e ija gbogbo agbaye ni ohun to n lọjẹ.

Ọrọ iwọde ENDSARS ko yọ awọn agbabọọlu paapa silẹ.

Lara awọn to ti fi ohun wọn si iwọde naa ni ogbontagi agbabọọlu fun Arsenal, Mesut Ozil ati Marcus Rashford.

Ozil ṣapejuwe ohun to n waye ni Naijiria gẹgẹ bi eyi to buru jai, to si yẹ ki o jẹ koko ọrọ nibi gbogbo.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Bakan naa lo fi ọrọ ikini ranṣẹ si gbogbo ẹni to ti kagbako ifiyajẹni ọlọpaa ni Naijiria.

Mesut Ozil

Oríṣun àwòrán, Mesut Ozil/instagram

Ni tiẹ, Rashford sọ pe oun n fi adura ati ero ọkan oun ṣe atilẹyin fun awọn ti iṣẹlẹ iwakiwa ọlọpaa kan ni Naijiria.

Yatọ si awọn wọnyi, oludasilẹ oju opo ayelujara Twitter, Jack Dorsey paapa ti fi atilẹyin rẹ fun ipolongo #ENDSARS, han.

O ṣe eyi nipa awọn ọrọ kan to kọ soju opo twitter rẹ pẹlu #ENDSARS.