End Sars, End SWAT, Aisha Yesufu: Ó ní ìdí tí mo fi ń wọ Hijabu lọ ṣe ìwọ́de- Aisha

Oríṣun àwòrán, other
Ọpọ eeyan lagbaye lo mọ Aishaa Yesufu gẹgẹ bi ajafẹtọ araalu ṣugbọn ohun ti o ṣokunkun si ọpọ ni idi ti o fi jẹ pe ẹwu hijab lo yan laayo lati maa wọ fun ti iwode #ENDSARS to gbode kan lọwọ yii.
Amosa, ẹ maa laagun jina o, Aishaa Yesufu funrarẹ ti ṣalaye idi abajọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Ninu ọrọ kan to ba BBC News sọ, Aishaa Yesufu ni aburo oun gan an lo kọkọ pe oun pe oun dabi eṣin o kọ'ku janduku ninu aworan oun ti wọn kọkọ ya nibi iwode naa ninu aṣọ yii.

Oríṣun àwòrán, others
Aisha ni ṣaaju aworan naa, ẹyin loun maa n duro si ki awon oluwode to jẹ ọdọ le e wa niwaju ki oun to wa ṣakiyesi pe awọn ọlọpaa kan fẹ maa dun mọhurumọhuru mọ wọn.
Aisha fi kun un pe awọn ọmọ oun gan a maa dara pọ mọ oun nibi iwọde biotilẹ jẹ pe ọkọ oun ko lẹmiu ki oju aye tan si eeyan lara.

Oríṣun àwòrán, Other
O ni ohun to fa sababi ti oun fi n wọ Hijabu lọ sode iwọde EndSARS ni pe ẹsin oun fi aye rẹ silẹ.
Islam, ẹsin ti mo yan laayo lo paṣẹ fun gbogbo obinrin lati maa bo ihoho wọn nibikibi ti wọn ba n lọ. Idi rẹ niyi ti mo fi n wọọ kaakiri, ṣugbọn eyi ko ni pe ki n yan ẹni ti ko ba wọọ ni pọṣin o.
Iwọde tako ẹka ọlọpaa SARS lorilẹ-ede Naijiria ṣi n tẹ siwaju lainaani ikede ti ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu ṣe ni ọjọ Abamẹta pe wọn ti wọgile ẹka SARS.
- Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò NBA ti kéde pé àwọn yóò ṣojú awọn Olùwọ́de #EndSARS lọ́fẹ̀ẹ́ nílé ẹjọ́
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà
- Ìjàmbá ọkọ̀ akérò àti tírélà pa èèyàn mẹ́rin lọ́nà mọ́rosẹ̀ Ore sí Benin
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Ọlọ́pàá mẹ́sàn án tó farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ Akure t'éèyàn méjì ti kú sì wà nílé ìwòsàn
















