EndSWAT: Wo àwọn Májẹ̀kóbàjẹ́ tó wà nídìí ìwọ́de #EndSARS / End SWAT

Oríṣun àwòrán, others
Iwọde End SARS to n lọ lọwọ kaakiri awọn ilu nla ni Naijiria ni ọpọ awọn onwoye ohun to n lọ ti sọ pe o jẹ ọkan Pataki lara awọn iwọde to ni eto julọ ni Naijiria.
Iwọde naa to ti n gbẹnule ọjọ kẹwaa bayii ni awọn ọdọ Naijiria fi n bere fun fifopin si iwa Baṣọrun Gaa ti awọn oṣiṣẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, SARS, n hu si awọn ọdọ ti wọn n fẹsun iwa jibiti kan lọna aitọ.
Bi ọpọ ero ṣe n darapọ mọ iwọde naa lojojumọ lawọn miran n gbe igbesẹ ki ifẹhonuhan ọhun dun, ko si larinrin.
Wo diẹ lara awọn to fi adun ati aṣeyọri si iwọde End SARS naa to n lọ lọwọ:
1.Awọn elere idaraya:
Ọkan lara awọn oluwọde naa gbe alupupu Power bike rẹ wa sojuko ọhun lati da awọn eeyan laraya.
Ni agbegbe Alausa, ẹnikan tilẹ gbe kẹkẹ ati aja rẹ wa, ti oun ati aja rẹ si n fi kẹkẹ ọhun dárà.
Yatọ si eyi, ọpọ igba ni wọn maa n fi awọn orin da awọn eeyan laraya, bii orin Fela Anikulapo, Naira Marley, Eedris Abdulkareem, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, others
2.Awọn to n kọ orin:
Ohun kan Pataki to mu iwọde End SARS ladun to si jẹ ki ijọba mọ ohun ti wọn n bere fun ni orin End SARS ti awọn oluwọde n kọ leralera.
Bi awọn to ṣaaju ṣe n kọ orin naa ni awọn elegbe n kọ tẹle wọn pe "End SARS!"
3.Awọn alasia:
Isọri awọn miran to jẹ ki iwọde End SARS ni itumọ ni bi awọn eeyan kan ṣe n gbe asia orile-ede Naijiria lojuko iwọde naa.

Oríṣun àwòrán, others
Ọkunrin lara awọn eeyan naa tilẹ ti di gbajumọ nitori bo ṣe maa n gbe asia naa to si ma n ju sọtun ati si osi.
Ni Enugu, ọdọbinrin kan tilẹ so asia naa mọ ori, o joko sori ere kan to ga to si n wa ẹkun mu nitori ohun ti awọn oṣiṣẹ SARS ti fi oju mọlẹbi rẹ ri.
4.Awọn onimọtoto:
Iyatọ kan gboogi to wa laarin iwọde End SARS yii ati awọn to ti kọja lọ ni bi awọn eeyan kan ṣe palẹmọ ojuko iwọde lẹyin ti awọn eeyan ba pada sile wọn tan.

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn eeyan naa n ṣe iṣẹ takuntakun lati ri pe ko si idọti Kankan lojuko ti iwọde ti n waye.

Oríṣun àwòrán, others
5.Awọn olupese:
Isọri awọn eeyan yii ni awon to n fun awọn olufẹhonuhan ni ounjẹ ki wọn ba a le ni okun lati tẹsiwaju ninun iwọde ọhun.
Awọn ni olupese ounjẹ, omi ati ohun irinsẹ fun awọn oluwọde, bi awọn kan ṣe parapọ da owo burẹdi ni awọn miran parapọ da owo DJ ti yoo da wọn laraya.

Oríṣun àwòrán, @Falz
6.Awọn oluṣeto:
Lara awọn oluṣeto ni awọn gbajumọ lawujọ to fi ẹnu si ọrọ naa, to si n ṣatilẹyin fun awọn olufẹhunuhan.
Diẹ lara awọn oluṣeto ni a ti ri olorin takasufe, oṣere tiata ati awọn gbajumọ kaakiri agbaye.
Awọn miran lara wọn gbe owo kalẹ fun iwọde naa, bẹẹ ni awọn mii ẹwẹ n ru wọn soke lati tẹsiwaju ninu iwọde ọhun.Lara awọn eeyan ọhun ni Falz, Toyin Abraham, Kanyew West, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, others

Oríṣun àwòrán, TWITTER/
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà
Iwọde ENDSARS to n lọ lọwọ ni Naijiria jẹ eleyi to milẹ titi.
Lati igba to ti bẹrẹ awọn ọmọ Naijiria ti tẹwọ gba a, ti wọn ni awọn yoo fi aato si ti yoo fi bi eso iyipada rere ti wọn n fẹ koda awọn to wa nilẹ okeere naa gbaruku ti wọn.
Orisirisi ni nkan to waye nibẹ ṣugbọn a ni ki a ṣe akojọpọ diẹ lara awọn ohun manigbagbe to waye nibẹ.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà
- Kíni ìyàtọ̀ tí yóò wà láàrin SARS àti SWAT?
- Mo ṣèlérí láti ṣe ju ohun tí mo ti ṣe lọ fún ẹbí àwọn tó kú torí EndSARS - Seyi Makinde
- Ìwọ́de 'End SARS' lè tan àjàkálẹ̀ arùn coronavirus lẹ́ẹ̀kejì ní Nàìjíríà- Ọjọ̀gbọ́n Faduyile
- Ẹ lo ìfẹ̀họ̀núhàn #EndSARS lati fí tún gbogbo ohun tó bàjẹ́ ṣe ní Naijiria- Pásítọ̀ Sam Adeyemi

Oríṣun àwòrán, veeQtor
Diẹ ree ninu wọn:
Awọn oluwọde pin feere fawọn obinrin
Feere pinpin fawọn obinrin ni ibi iwọde Lekki jẹ nkan tawọn eeyan kan saara si.
Ohun ti wọn fi ṣe bẹẹ ree.
Niṣe ni awọn eeyan kan n fi ọwọ kan awọn obinrin lọna aitọ nibi iwọde nitori naa ni wọn fi fun wọn ni feere pe ki wọn fi pariwo sita.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Iwọde ko ni k'awọn eeyan ma sokun ifẹ pọ; ki wọn tun ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi
Iwọde yii ti bi ọmọ orisirisi.
Bi awọn kan ti ṣe ya sidi ijo ati orin lawọn mii fi asiko iwọde polongo ifẹ ti awọn mii tiẹ sokun ifẹ pọ.
Koda awọn to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi wọn laarin awọn oluwọde wa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/diranabiola
Awọn aworan bi eyi to wa labẹ yi ṣafihan awọn to ṣe ọjọ ibi ati awọn to pari igbeyawo gẹgẹ bii tọkọtaya tuntun ti a so pọ ti wọn si gba ibẹ lọ si iwọde.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Awọn to n fi ẹbun ta oluwọde ati agbofinro lọrẹ naa ko gbẹyin:
Lasiko iwọde #End SARS yii naa ni awọn ọmọ Naijira n nawọ iranwọ sawọn oluwọde.
Bi wọn ti ṣe n gbe ounjẹ ati omi ni awọn kan n fi nkan eelo itọju alaisan to fi mọ ibomu ṣọwọ si awọn oluwọde.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Nilu Abuja awọn oluwọde fi imoore han plu bi wọn ti ṣe fi aworan arakunrin kan ti wọn lo fun awọn ni ounjẹ lasiko iwọde naa han lori ayelujara
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Yatọ si eyi, awọn oluwọde tun fun awọn agbofinro ni omi mu laibikita pe wọn n koju awọn.
Koda, wọn nawọ ifẹ ati iranlọwọ si awọn agbofinro pe iwọde yii a bi eso atunṣe owo oṣu fun awọn ọlọpaa ti ijọba ba gba ohun ti awọn oluwọde n fẹ ki alaafia ati abo to peye le wa fun gbogbo olugbe Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Twitter/AmDanky
Ibi taa ti n ṣe iwọde, imọtoto naa ṣe pataki
Akojọpọ awọn eeyan maa n mu ki awọn eeyan da panti silẹ boya lẹyin ti wọn jẹun tan tabi ti wọn ba mu ohun mimu tan.

Oríṣun àwòrán, veeQtor
Kaakiri ibi iwọde ni awọn ọdọ ti ṣe ohun iyalẹnu kan pẹlu bi wọn ti ṣe n ko panti lẹyin ti wọn ṣe iwọde tan.
Niṣe ni awọn ọdọ Naijiria kan fi ara wọn jin lati maa ṣa awọn idọti lẹyin awọn iwọde lojoojumọ.

Oríṣun àwòrán, Gidi_Traffic
Iwa yi jẹ eleyi to mu inu ọpọ eeyan dun ti wọn si n kan saara sawọn oluwọde naa
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Taa lo sọ foonu nuu?
Nibi tero ba pọ si o ṣeeṣe ki eeyan sọ nkan nu tabi ko gbagbe nkan si eeyan mii lọwọ.
Lasiko iwọde yi awọn eeyan sọ nkan nu paapaa lasiko ti o ba di pe wọn n sa fun awọn agbofinro.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
- Ọlọ́pàá mú afurasí 31 tó ń dúnkokò máwọn ọmọdé lórí ayélujára
- Bàbá ọlọ́mọ méjì fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lò pọ̀; Adájọ́ rán an ní ẹ̀wọ̀n gbére
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- Ẹ lo ìfẹ̀họ̀núhàn #EndSARS lati fí tún gbogbo ohun tó bàjẹ́ ṣe ní Naijiria- Pásítọ̀ Sam Adeyemi
Nibi tawọn eeyan ti n sa yi, awọn mii sọ foonu ati nkan ini wọn nuu.
Amọ ṣa bi wọn ti ṣe n sọ nkan nuu naa ni awọn to ri n da pada fun wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7

End of X post, 8