ENDSARS: Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ́yìn ṣùgbọ́n...

SARS picture

Oríṣun àwòrán, Police

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oga Agba ọlọpaa, Muhammed Adamu ti kede pe ijọba ti tu ikọ ọlọpaa SARS ka lẹyin ti awọn eniyan ko dawọ duro lori ifẹhọnu han ti wọn n ṣe pẹlu asia #EndSARS.

Amọ kii ṣe igba akọkọ ni yii ti Ọga ọlọpaa yoo tu ikọ SARS ka, ati wi pe igba kẹrin leleyii.

Akojọpọ re e lori igba mẹrin ti ikọ ọlọpaa ti tu SARS ka lorilẹede Naijiria.

Ọjọ Kẹrin, Oṣu kẹwaa, ọdun 2020

Ọga agba ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Asamu paṣẹ ki ikọ FSARS ye e kaakiri lati ma a wo ọkọ ati dukia awọn eniyan mọ loju popo, tabi ki wọn ma a gbe ọkọ kaakiri lati fi ṣe ọṣẹ.

Amọ, ikọ SARS ko dawọ duro rara nitori wọn ko jawọ ninu irinkerindo wọn, tabi wiwu iwa ipa si awọn araalu.

SARS

Oríṣun àwòrán, NPF

Osu Keji, ọdun 2020

Lẹyin ti ọlọpaa pa ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars, Tiamiyu Kazeem ni ilu Sagamu, nipinlẹ Ogun ni IGP Mohammed Asamu sọ wi pe ki wọn ti gbogbo ileese ikọ SARS kaakiri orilẹede Niajiria.

Ni igba naa, igbakeji ọga ọlọpaa to n risi iwa ọdaran lawujọ, Peter Ogunyonwo lo kede rẹ lasiko ti wọn n ba awọn ẹbi Tiamiyu kẹdun lẹyin iku ọmọ wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Niajiria ṣe apejuwe ikọ SARS naa gẹgẹ bi agbekalẹ to ni aṣiṣe ninu.

EndSARS:

Oríṣun àwòrán, Remo Stars/Police

Oṣu Kini, ọdun 2019

Ọga Agba ọlọpaa lorilẹede Niajiria to jẹ adele nigba naa, Mohammed Adamu lo tu ikọ SARS ti ijọba apapọ ka patapata( ohun kan naa lo ṣe ni Oṣu Kẹwaa, ọdun 2020).

Ọga Adamu paṣẹ fun gbogbo awọn kọmiṣọnna ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria lati ri pe wọn tu ikọ naa ka.

Bakan naa ni ọga ọlọpaa naa paṣẹ fun olu ilu ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Abuja lati tu ikọ SARS ti Abuja ka.

EndSARS

Ọṣu Kẹjọ, ọdun 2018 ni wọn da ikọ FSARS silẹ

Ni ọdun 2018 ti wọn da ikọ SARS silẹ, ohun ti wọn sọ ni wi pe awọn wọnyii ko ni ma a da awọn eniyan duro lọna, lati ma wo ohun ti wọn gbe sinu ọkọ.

Ikọ ọlọpaa si fikun wi pe ọlọpaa to ba ṣe aṣemaṣe yoo fi oju wina ofin laarin wakati mẹrindinlogun.

Amọ titi di asiko yii, ko si ohunkohun to yi pada.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Nigeria Police

Oríṣun àwòrán, YASUYOSHI CHIBA

Ni ọdun 2017, bakan naa ni Ọga Ọlọpaa tẹlẹ, Ibrahim Idris fi opin si ki ọlọpaa ma a da awọn eniyan duro wi pe wọn fẹ wọ ohun ti wọn gbe.

Aṣẹ ti ọga ọlọpaa gbe jade naa ni wi pe gbogbo awọn ọlọpaa to ba n ṣiṣẹ ni ẹka naa, ki wọn jawọ ninu rẹ.

Bakan naa ni IGP nigba naa paṣẹ ki awọn ọlọpaa ma a wọ aṣọ iṣẹ wọn pẹlu ami idanimọ lasiko iṣẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria da ikọ naa silẹ lati le koju ole jija ati iwa ọdaran lawujọ.

Àkọlé fídíò, Abayọmi Aranmọlatẹ, Dr Laser: Vagino Plasty àti iṣẹ́ abẹ ẹwà Obìnrin ló jẹ mí lógún

Saaju ni ijọba ti kọkọ kede ifopin si SARS

ENDSARS: Wo ohun márùn-ún tí yóò ṣẹlẹ̀ bí ìjọba ṣe tú SARS ká

Ọga agba ajọ ọlọpaa ni wọn yoo gbe gbogbo awọn agbofinro naa to n ṣiṣẹ ni ikọ SARS lọ si ẹka mii nileeṣẹ ọlọpaa kan naa.

Ọga agba ajọ ọlọpaa tun ni wọn yoo ṣe ilana tuntun jade fun awọn ọlọpaa lori kikoju awọn adigunjale atawọn iwa ipa mii.

Aworan oluwọde endsars

Oríṣun àwòrán, Twitter/aminuyaro_

O ni awọn yoo gbe igbimọ araalu atawọn alẹnulọrọ kalẹ lati pese anfani fawọn araalu lati maa foju gaani ati lati maa gba awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lori awọn ọrọ nla to kan araalu.

Lati lee koju awọn iwa aidaa si awọn araalu, awọn yoo ṣe agbekalẹ ikọ aṣewadii ti awọn ẹgbẹ araalu ti awọn yoo si maa fi awọn ti igba iwa yii ba ṣi mọ lori jofin.

Ọga ọlọpaa tun tẹnumọ igbaradi ileeṣẹ ọlọpaa lati fi orukọ rere pe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria to fi mọ aato nilana ikọṣẹmọṣẹ fun ṣiṣe iṣẹ wọn fun awọn araalu.

EndSARS: Wo ohun táwọn gbajúgbajà tó n darí ìwọ́de ìfopinsí FSARS n sọ

Gbogbo igboro Naijiria lo ti kun fun ajọyọ paapaa laarin awọn ọdọ nitoripe ohun ti wọn n bere fun lọwọ ijọba papa tẹ wọn lọwọ.Awọn gbajugbaja laarin awọn ọdọ Naijiria bii olorin, oṣere, adẹrinpoṣonu lo dide lati dari awọn ọdọ akẹgbẹ wọn.

Lẹyin ọpọlọpọ igba ti awọn ọmọ Naijiria ti n fọnmu lori pe ki ijọba gbe igbesẹ lori bi awọn ikọ agbofinro SARS ṣe n ṣe awọn araalu lọṣẹ ni aṣeyọri yi to waye.

Nibayii ti ijọba ati ọga agba ọlọpaa ti jẹ awọn ọdọ ni hoo, ajọyọ tun bẹrẹ ti awọn kan si tun ni ọrọ lati sọ fun ijọba."Yipeeeeee" pẹlu aworan ijo lẹsẹ ni gbajugbaja oṣere, Toyin Abraham fi ṣafihan ajọyọ rẹ loju opo instagram.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Ni ti olorin Falz, o fi ye awọn ọdọ Naijiria pe "eyi ni agbara ti ẹ ni. Ẹyin ati emi lapapọ. Ibẹrẹ ọtun ree"

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Runtown ṣe atunpin atẹjade ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ Buhari to kede ọga agba ọlọpaa ti tu ikọ SARS ka. O kọ akọle tirẹ pe "bi a ba wa papọ, a ni okun".

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Gbajugbaja oṣere Yoruba mii, Iyabo Ojo ni "ẹ bori ninu eyi na! A bori! O fi ye wa pe agbara wa ninu fifohunṣọkan.''

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 4

O wi fun awọn ọdọ Naijiria pe bi wọn ba si wa ko awọn ikọ SARS pada wa, a o tun tẹsiwaju ninu ifẹhonuhan".

Aworan ọga ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigerioa Police Force

Ìdí tí ìjọba fi tú FSARS ká rèé!

Ijọba apapọ Naijiria ti paṣẹ ki wọn tu ikọ ọlọpaa FSARS ka ni kiakia.

Ọga patapata ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Mohammed Adamu lo kede ọrọ yi nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aiku.

Adamu sọ pe igbesẹ yi jẹ idahun si igbe tawọn ọmọ Naijiria n pa lori ikọ naa.

Orisi ẹsun ni awọn ara ilu fi kan awọn agbofinro yii kaakiri Naijiria ati ni ilẹ okeere nibi ti iwọde ti waye kaakiri.

Adamu ni bẹrẹ lati wakati yi, gbogbo awọn oṣiṣẹ ikọ yi ni wọn yoo darapọ mọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa mi.

Loju opo Twitter wọn, alukoro ọlọpaa Frank Mba ṣalaye koko marun un ti iyipada yi yoo tẹle.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ileeṣẹ Aarẹ Naijiria naa fi ikede yi sita loju opo wọn ni Twitter.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Lẹnu ọjọ mẹta yi ni ariwo ati iwọde bẹrẹ si ni gbalẹ tawọn eeyan Naijiria si ni ki ijọba tu FSARS ka.

Ijọba ni ko si ohun to n jẹ FSARS mọ ni gbogbo ipinlẹ mẹrindinlọgbọn to wa ni Naijiria ati ni Abuja

Ijọba ni awọn yoo pin awọn agbofinro ẹka FSARS yii kaakiri ẹka ileeṣẹ ọlọpaa miran.

Ijọba ni awọn yoo kede ẹka ọlọpaa miran ti yoo ma gbogun ti awọn adigunjale.

Ijọba ni ajọ agbofinro ati ara ilu tuntun ni awọn yoo ṣe agbekalẹ re lati ma risi ẹsun to ni i ṣe pẹlu ara ilu.

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn