Ondo election 2020: Gómìnà Akeredolu la Jegede mọ́lẹ̀ wọlé ìbò gómìnà Ondo fún sáà kejì

Buhari ati Aketi

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammed Buhari ti ki gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ku oriirẹ pẹlu bi o ṣe jajabọ ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ondo.

Aarẹ Buhari fi eyi lede gba ọwọ oluranlọwọ pataki ninu eto iroyin igbalode, Bahir Ahmad, eleyii to fi si oju opo Twitter.

BUHARI

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ni '' Akeredolu ku orire iyansipo gẹgẹbi gomina fun ọdun mẹrin miran lati tukọ ipinlẹ Ondo''.

Buhari and Aketi

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Akeredolu ti ẹgbẹ oṣelu APC la Jedege mọlẹ pẹlu ibo 29,2830, ti Jegede ti ẹgbẹ oṣelu PDP si ni ibo 195,791.

''A kò gbà pé Eyitayo Jegede fìdírẹmi, Àjọ INEC ló ṣe aṣemáṣe''

Awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni awọn ko gba wi pe Eyitayo Jegede fidirẹmi, amọ ajọ eleto idibo INEC lo ṣe magomago fun wọn.

Eyitayo Jegede

Oríṣun àwòrán, Facebook

Eyi ko ṣẹyin bi Ajọ INEC ṣe kede gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo sipo gomina nipinlẹ Ondo.

Bakan naa ni alukoro ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ondo, ni awọn ṣi n gba alaye lori esi idibo naa lọwọ nitorinaa awọn ko tii le fesi.

''Eyitayo Jegede naa ko i tii ṣetan lati sọrọ lori esi idibo naa, ti asiko ba to, yoo sọrọ''

Ololufẹ Eyitayọ Jegede miran to sọrọ ni oun ko tun ṣe oṣelu mọ lẹyin bi Eyitayọ Jegede ṣe fidirẹmi.

Lasiko ti akọroyin BBC kaakiri agbegbe Eyitayo Jegede, ni ṣe lo pa lọlọ ti ko si si ẹni to n dunnu ni agbegbe naa.

Ìfẹ́ tí mo ní sí aráàlú ló gbé mi wọlé lẹ́ẹ̀kejì - Gomina Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti ni ifẹ ti oun ni si awọn araalu lo jẹ ki wọn dibo fun oun gẹgẹ bi gomina fun saa keji.

Gomina Akeredolu sọ eyi lasiko to jawe olubori ninu didbo sipo gomina ni ipinlẹ Ondo.

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Akereolu/Facebook

Akeredolu tun dupe lọwọ aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo fun atilẹyin wọn saaju ati lasiko idibo naa.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi, Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ibikunle Amosun,gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, gomina ipinlẹ Kebbi ati gomina ipinlẹ Jigawa.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ Lucky Ayedatiwa to dije gẹgẹ bi igbakeji gomina, to si rọ ki o maṣe da oun lẹyin o rẹyin.

O tun dupẹ lọwọ awọn ti wọn jọ dije dupo labẹle pe wọn ba oun ṣiṣẹ.

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rotimi Akeredolu

Ninu ọrọ tirẹ, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ni ibi giga ni ipinlẹ Ondo n lọ, nitori naa ki wọn ma a gbadura fun un lati mu gbogbo ileri rẹ ṣẹ.

Gómìnà Akeredolu la Jegede mọ́lẹ̀ wọlé ìbò gómìnà Ondo fún sáà kejì

Gomina Rotimi Akeredolu ti wọle ibo gomina ipinlẹ Ondo to waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Akeredolu to jẹ oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC la oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayo Jegede to sun mọ ọ julọ ninu eto idibo naa mọlẹ.

Eyi tumọ si pe Akeredolu ti wọle ibo gomina ipinlẹ Ondo bayii fun igbakeji.

Akeredolu lo moke ninu ijọba ibilẹ to pọ julọ ni ipinlẹ Ondo nigba ti Jegede oludije PDP atawọn to ku si tẹ le e.

Ninu esi idibo awọn ijọba ibilẹ ti wọn kọkọ ka, APC moke ninu ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa ni Ondo.

Akeredolu ati igbakeji

Oríṣun àwòrán, @Akeredolu

Àkọlé àwòrán, Akeredolu ati igbakeji rẹ

Akeredolu lo gba ju bẹrẹ lati ijọba ibilẹ Akoko North West, Akoko North East, Akoko South East ati Akoko South West.

Àkọlé fídíò, coronavirus prevention badge update: Wo òótọ́ àti irọ́ tó wà nínú báàjì àyà náà

Awọn yoku ni Ile Oluji/Okeigbo, Owo, Idanre ati Ondo East.

Awọn ijọba ibilẹ ti PDP ti moke ni ijọba ibilẹ Ifedore, Akure North ati Akure South.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin ni kopẹ kopẹ.

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn