Ìdí tí o kò fi gbọdọ̀ pa oríṣi inú rírun márùn-ún yii mọ́ra

Oríṣun àwòrán, @others
Inu dídùn tabi rírun jẹ ọkan lara awọn ipenija eto ilera to wọpọ, debi i pe awọn eeyan kan kii saba kọbi ara si.
Awọn onimọ nipa ilera si ti sọ pe inu rirun tabi didun le jẹ atọ́ka si aisan to lagbara, to si le ju bose yẹ lọ ti ko ba tete si amojuto ni ibẹrẹ pẹpẹ.
Dokita Anigbamkpu Obinnaadigo, sọ fun BBC pe inu rirun le jẹ àpẹẹrẹ aisan bi òkúta inu kíndìnrín, appendicitis, iba jẹdọjẹdọ (typhoid) àti ọgbẹ́ inu.
- Kọ́ sí i nípa àwọn oúnjẹ aṣaralóore tó yẹ kí Aláboyún máa jẹ
- Afurasí Boko Haram pa ológun àti ọlọ́pàá mẹ́rìnlá ní Borno
- Ẹ wá ná, kí ló ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú APC àti Kayode Fayemi ní Ekiti gan an?
- Kò sí iléẹjọ́ tó le dá wa dúró, ìyanṣẹ́lódì yóò bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Ajé - NLC
- Wo iye ìgbà tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àtàwọn ọmọ Nàìjíríà ti ṣèwọ́de lórí àfikún owó epo bẹntírò
- Ìbúgbàmù gbogbo ìgbà nílù ú Èkó, kí ló ń ṣokùnfà rẹ̀?
- Ẹ wá ná, kí ló ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú APC àti Kayode Fayemi ní Ekiti gan an?
Appendicitis
Dokita Obinnaadigo ṣalaye pe àpẹẹrẹ akọkọ ti aisan appendicitis ma n fihan ni ki isalẹ inu o ma a dun eeyan.
To ba ya, ìrora naa yoo bọ si ẹgbẹ osi ni isalẹ ikun. To ba ti de ipele yii, isẹ abẹ ni ọna abayọ, ki okuta naa ma ba a tú sinu ikun.
"O wọpọ fun awọn eeyan lati ma a lo oogun ara riro, ti inu ba n dun wọn. Amọ, eyi kan ma n din irora ku ni, kii ṣe itọju fun orisun tabi nkan to fa irora."
Dokita Obinnaadigo sọ pe ti wọn ko ba tete ṣe ayẹwo lati mọ nkan to n fa inu dídùn, o le yọrí si ki appendix ko lu iho jade," eyi si lewu pupọ".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọgbẹ́ inu (Gastric ulcer):
Aisan yii ma n bẹrẹ ti eroja to n mu ki oúnjẹ o da ninu ikun, ba n jẹ awọ ikùn, eyi ti yoo fa ọgbẹ́.
Dokita Obinnaadigo sọ pe aaye to wa laarin aya ati ikun ni irora aisan ọgbẹ́ inu.
Awọn oúnjẹ to si saba ma n fa irora rẹ ni oúnjẹ to ni ata pupọ, oúnjẹ ti wọn din, ati ki eeyan fi ebi pa inu fun igba pipẹ.
Okuta inu kindinrin:
Aisan yii ma n fi ara rẹ han bi irora ni ẹyin ikùn, o le jẹ ni ẹgbẹ ọtun tabi ti òsì. Eyi nii ṣe pẹlu kindinrin to ba n ṣe aisan.
Dokita Obinnaadigo sọ pe irora naa yoo wa fun igba diẹ, ko tun to o lọ silẹ.
Ati pe ni kiakia ni ki ẹni to ba ni iru irora yii lọ sileewosan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Inu rirun lasiko nkan oṣu:
Nkan oṣu obinrin naa ma n fa inu rirun.
Dokita Obinnaadigo sọ pe ko si ẹri tabi alaye ninu iṣegun oyinbo to ṣalaye idi ti awọn obinrin kan fi ma n ni irora lasiko nkan oṣu, tabi idi ti awọn miran kii fi i ni irora.
Sugbọn sa, eeyan gbọdọ lọ sileewosan fun ayẹwo, ti irora nkan oṣu ba kọja bose yẹ.

Oríṣun àwòrán, Chiagozie Nwonwu
Inu rirun ninu oyun:
"Ko yẹ ki aboyun ni irora kankan, ayaafi ti nkan ko ba ri bo ṣe yẹ."
Dokita Obinnaadigo sọ pe inu rirun ninu oyun le jẹ ami pe nkan ti fẹ ẹ yiwọ, ninu eyi to le jẹ pe oyun naa n dagba ni ita ile ọmọ obinrin - ectopic pregnancy, ni awọn onimọ nipa ilera n pe e.
Idi si niyii ti awọn eleto ilera ṣe ma n sọ pe o ṣe pataki fun alaboyun ti inu ba n run lati lọ ri dokita.
- Èkúté tó sàwárí bọ́mbù ilẹ̀ gbàmi ẹ̀ye wúrà fún iṣẹ́ takuntakun
- Ẹ gbọ́ òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa Bàbá ìsàlẹ̀...
- Nǹkan yan, àwọn aṣẹ́wó fẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀ nítorí ẹ̀kúnwó epo ní Nàìjíríà
- Àwọn tó fẹ́ kí ọba máa ta ilẹ̀ ilú ló fẹ́ yọ Oluwo lóyè- Ẹgbẹ̀ Baálẹ̀ Iwo.
- Ọlọ́pàá kọlu àwọn ọmọ onílẹ̀, ní ìbọn àṣìyìn pa ènìyàn méjì


















