Fuel price hike: Wo iye ìgbà tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àtàwọn ọmọ Nàìjíríà ti ṣèwọ́de lórí àfikún owó epo bẹntírò

Awọn olofẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Twitter/@ayemojubar

Ẹgbẹ apapọ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, Nigeria Labour Congress(NLC) ti kede pe ohun yoo gunle iwọde lọjọ Aje ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹsan an lati fi ẹhonu han lori afikun owo epo bẹntiro ati ina ọba.

Igbimọ alaṣẹ NLC buwọlu igbesẹ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa lati bẹrẹ iwọde kaakiri orilẹede Naijiria lọjọ Aje to n bọ.

Lẹyin ti ijọba apapọ yọ owo iranwọ ori epo tan lo ṣe afiukun owo epo bẹntiro lati N145 si N161 to wa bayii.

Bakan naa ni ijọba kede afikun owo ina ọba lọna ilọpo meji eyi ti o mu ki ọpọ araalu ṣi maa ke pe inira nla lo jẹ fawọn.

Wọnyii ni iye igba ti ẹgbẹ oṣiṣẹ atawọn ọmọ Naijiria ti fẹhonuhan lori afikun owo epo bẹntiro lati ọdun 2003 ti Naijiria ti pada si ijọba awarawa.

Àkọlé fídíò, Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

Ifẹhonuhan lori afikun owo epo ọdun 2003

Ẹgbẹ apapọ oṣiṣẹ, NLC labẹ olori rẹ nigba naa, Adam Osiomole gunle iyanṣẹlodi pẹlu iwọde lẹyin ti ijọba aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Olusegun Obasanjo ṣe afikun owo epo bẹntiro lati N26 naira lọ si N40.

Ijọba Obasanjo ṣalaye pe afikun owo epo waye nitori ijọba ṣe adinku owo iranwọ to wa lori ero.

Ijọba sọ pe ohun yoo na owo to ba jade lati ibẹ sori ẹka eto ẹkọ ati ilera.

Awọn oṣiṣẹ bẹrẹ iyanṣẹlodi pẹlu iwọde kaakiri orilẹede Naijiria.

Lọjọ kẹjọ oṣu keje ọdun 2003 lẹgbẹ NLC kede pe ohun wọgile le iyanṣẹlodi to gunle lẹyin to faramọ igbesẹ ijọba lati gbe owo epo si N34 lati N40.

@Ayemojubar

Oríṣun àwòrán, Twitter/@ayemojubar

Ifẹhonuhan lori afikun owo epo ọdun 2004

Iyansẹlodi ati ifẹhonu han tun bẹrẹ lọdun 2004 lẹyin ti ijọba Obasanjo tun ṣe afikun owo epo bẹntiro lati N40 si N45.

Awọn ileewe, banki, ọfiisi ati ọpọlọpọ okoowo lo di titi pa lẹyin ti ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC bẹrẹ iyaṣẹlodi kaakiri Naijiria.

Niluu Eko fun apẹẹrẹ, awọn olufẹhonukan bọ si oju titi ṣugbọn awọn ọlọpaa yin tajutaju soke lati tu wọn ka.

Awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ sẹ ipade pẹlu ijọba Obasanjo, ṣugbọn ijọba fi aake kọri pe igbesẹ ohun ṣe pataki lati mu atunṣe ba ẹka eto ifọpo ni Naijiria.

Ifẹhonuhan lori afikun owo epo ọdun 2007

Ijọba Obasanjọ tun ṣe afikun owo epo bẹntiro lati N45 lọ si N70.

Eyi lo fa iyanṣẹlodi pẹlu iwọde kaakiri orilẹede Naijiria lọdun 2007.

Awọn olufẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Omoyele Sowore

Gbogbo ileeṣẹ nla nla lo kogba sile, awọn oṣiṣẹ banki atawọn oṣiṣẹ ijọba ko lọ di ibi iṣẹ.

Lawọn agbegbe kan, awọn ọdọ n gba bọọlu loju titi lẹyin toju popo da paro paro.

Ijọba dunkoko mawọn ẹgbẹ oṣisẹ pe iyanṣẹlodi tawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ gunle lodi si ofin, amọ wọn ni awọn ko ni wọgile iyanṣẹlodi ọhun ayafi ti ijọba ba mu afikun owo epo naa kuro.

Ijọba aarẹ ana to ti di oloogbe, Umar Yar'Adua lo pada ṣe adinku owo epo naa, to si gbe lọ si N65.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lóri BBC Yoruba

Ifẹhonuhan lori afikun owo epo ọdun 2012

Ọjọ kinni oṣu kinni ọdun 2012 ni ijọba Good luck Jonathan kede pe ohun ti mu owo iranwọ ori epo(subsidy) kuro.

Eyi lo mu ki ijọba gbe owo epo bẹntiro lọ si N141 lati N65, lẹyin naa lawọn eeyan bẹ sita ti wọn si bẹrẹ ifẹhonuhan kaakiri orilẹede Naijiria.

Awọn olofẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Twitter/@Ayemojubar

Ọjọta lawọn olufẹhonuhan fi ipade si niluu Eko, oniruuru awọn ajafẹtọ lo pade nibẹ nibi ti wọn ti n kọrin a ko nii gba si ijọba Jonathan leti.

Awọn sọja ni ijọba da sita lati le awọn olufẹhonuhan kuro loju titi kaakiri Naijiria.

O kere tan. akọsilẹ fihan pe eeyan mẹẹdogun lo ba iwọde naa lọ lọdun 2012.